Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 6:9-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Ṣùgbọ́n àwọn kan dìde nínú àwọn ti ń se ara sínágógù, tí a ń pè ní Líbátaínì. Àwọn Júù Kírénè àti ti Alekisáńdíríà àti ti Kílíkíà, àti ti Ásíà wá, wọ́n ń bá Sítéfánù jiyàn,

10. ṣùgbọ́n wọn kò sí lè ko ọgbọ́n àti Ẹ̀mí tí ó fi ń sọ̀rọ̀ lójú.

11. Nígbà náà ni wọ́n fún àwọn ọkùnrin kan ní àbẹ̀tẹ́lẹ̀, kí wọn ń wí pé, “Àwa gbọ́ tí Sítéfánù ń sọ ọ̀rọ̀-òdì sí Mósè àti sí Ọlọ́run.”

12. Wọ́n sí ru àwọn ènìyàn sókè, àti àwọn alàgbà, àti àwọn olùkọ́ni ní òfin. Wọ́n dìde sí i, wọ́n gbá a mú, wọ́n sì mú un wá sí iwájú àjọ ìgbìmọ̀.

13. Wọ́n sí mú àwọn ẹlẹ́rìí èké wá, ti wọn wí pé, “Ọkùnrin yìí kò sinmi láti sọ ọ̀rọ̀-òdì sí ibi mímọ́ yìí, àti sí òfin.

14. Nítorí àwa gbọ́ o wí pé Jésù ti Násárẹ́tì yìí yóò fọ́ ibí yìí, yóò sì yí àṣà ti Mósè fifún wa padà.”

15. Gbogbo àwọn tí ó sì jókò ni àjọ ìgbìmọ̀ tẹjúmọ́ Sítéfánù, wọ́n sì rí ojú rẹ̀ dàbí ojú ańgẹ́lì.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 6