Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 5:6-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Àwọn ọdọ́mọkùnrin sí dìde, wọ́n dì í, wọn sì gbé è jáde, wọn sì sin ín.

7. Ó sì tó bí ìwọ̀n wákàtí mẹ́ta, aya rẹ̀ láìmọ̀ ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀, ó wọlé.

8. Pétérù sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Wí fún mi, ṣé iye yìí ni ìwọ àti Ananíyà gbà lórí ilẹ̀?”Ó sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, iye rẹ̀ nìyẹn.”

9. Pétérù sí wí fún un pé, “È é ṣe ti ẹ̀yin fohùn sọ̀kan láti dán Ẹ̀mí Mímọ́ wò? Wò ó, ẹsẹ̀ àwọn tí ó sìnkú ọkọ rẹ ń bẹ lẹ́nu ọ̀nà, wọn ó sì gbe ìwọ náà jáde.”

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 5