Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 5:27-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

27. Nígbà tí wọn sì mú àwọn àpósítélì dé, wọn mú wọn dúró níwájú àjọ ìgbìmọ̀; olórí àlúfáà sì bi wọ́n léèrè.

28. Ó wí pé, “Àwa kò ha ti kìlọ̀ fún un yín gidigidi pé, kí ẹ má ṣe fi orúkọ yìí kọ́ni. Ṣíbẹ̀ ẹ̀yin ti fi ìkọ́ni yín kún Jerúsálémù, ẹ sì ń pete àti mú ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ ọkùnrin yìí wá sí orí wá.”

29. Ṣùgbọ́n Pétérù àti àwọn àpósítélì dáhùn, wọ́n sì wí pé, “Àwa kò gbọdọ̀ má gbọ́ tí Ọlọ́run ju ti ènìyàn lọ!

30. Ọlọ́run àwọn baba wa jí Jésù dìde kúrò ní ipò òkú, ẹni tí ẹ̀yin pa nípa gbígbé kọ́ sí orí igi.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 5