Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 5:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ṣùgbọ́n ọkùnrin kan ti a ń pè ni Ananíyà, pẹ̀lú Sàfírà aya rẹ̀, ta ilẹ̀ ìní kan,

2. Nípa ìmọ̀ aya rẹ̀ ó yan apákan pamọ́ nínú owó náà, ó sì mú apákan rẹ̀ wá, ó sì fi í lélẹ̀ lẹ́sẹ̀ àwọn àpósítélì.

3. Ṣùgbọ́n Pétérù wí pé, “Ananíyà, È é ṣe ti sátánì fi kún ọkàn rẹ láti ṣèké sí Ẹ̀mí-Mímọ́, tí ìwọ sì fi yan apákan pamọ́ nínú owó ilẹ̀ náà?

4. Nígbà tí ó wà níbẹ̀ tìrẹ kọ́ ní í ṣe? Nígbà tí a sì ta á tan, kò ha wà ní ìkáwọ́ rẹ̀? È é há ti ṣe tí ìwọ fi rò nǹkan yìí lọ́kàn rẹ? Ènìyàn kọ́ ni ìwọ ṣékè sí bí kò ṣe sí Ọlọ́run?”

5. Nígbà tí Ananíyà sí gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó subú lulẹ̀, ó sì kú, ẹ̀rù ńlá sí ba gbogbo àwọn tí ó gbọ́.

6. Àwọn ọdọ́mọkùnrin sí dìde, wọ́n dì í, wọn sì gbé è jáde, wọn sì sin ín.

7. Ó sì tó bí ìwọ̀n wákàtí mẹ́ta, aya rẹ̀ láìmọ̀ ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀, ó wọlé.

8. Pétérù sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Wí fún mi, ṣé iye yìí ni ìwọ àti Ananíyà gbà lórí ilẹ̀?”Ó sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, iye rẹ̀ nìyẹn.”

9. Pétérù sí wí fún un pé, “È é ṣe ti ẹ̀yin fohùn sọ̀kan láti dán Ẹ̀mí Mímọ́ wò? Wò ó, ẹsẹ̀ àwọn tí ó sìnkú ọkọ rẹ ń bẹ lẹ́nu ọ̀nà, wọn ó sì gbe ìwọ náà jáde.”

10. Lójúkan náà ó sì ṣubú lulẹ̀ lẹ́sẹ̀ rẹ̀, ó sì kú; àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sì wọlé wọ́n bá a ní òkú, wọ́n sì gbé e jáde, wọ́n sín in lẹ́bá ọkọ rẹ̀.

11. Ẹ̀rù ńlá sì bá gbogbo ìjọ àti gbogbo àwọn tí ó gbọ́ nǹkan wọ̀nyí.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 5