Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 28:23-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Àwọn fi ẹnu kò lórí ọjọ́ tí wọn yóò se ìpàdé pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù, ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ni ó tọ̀ ọ́ wa ni ilé àgbàwọ̀ rẹ̀; àwọn ẹni tí òun sọ àsọyé ọ̀rọ̀ ìjọba Ọlọ́run fún, ó ń yí wọn padà nípa ti Jésù láti inú òfin Mósè àti àwọn wòlíì, láti òwúrọ̀ títí ó fi di àṣálẹ́.

24. Àwọn ẹlòmíràn gba ohun tí ó wí gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlòmíràn kò sì gbà á gbọ́.

25. Nígbà tí ohùn wọn kò ṣọ̀kan láàrin ara wọn, wọ́n túká, lẹ́yìn ìgbà tí Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ kan pé, “Ẹ̀mí Mímọ́ sọ òtítọ́ fún àwọn baba yín nígbà tí ó sọ láti ẹnu wòlíì Àìṣáyà wí pé:

26. “ ‘Tọ àwọn ènìyàn wọ̀nyí lọ, kí ó sì wí pé,“Ní gbígbọ́ ẹ̀yin yóò gbọ́, kì yóò sì yé e yín;à ti ni rírí ẹ̀yin yóò rí, ẹ kì yóò sí òye lati mọ̀.”

27. Nítorí ti àyà àwọn ènìyàn yìí yigbì,etí wọn sì wúwo láti fi gbọ́,ojú wọn ni wọn sì ti di.Nítorí kí wọn má ba à fi ojú wọn rí,kí wọn má ba à fi etí wọn gbọ́,àti kí wọn má ba à fi ọkàn wọn mọ̀,kí wọn má ba à yípadà, àti kí èmi má ba à mú wọn láradá.’

28. “Ǹjẹ́ kí ẹ̀yin mọ́ èyí pé, a rán ìgbàlà Ọlọ́run sí àwọn Kèfèrì wọ́n ó sì gbọ́.

29. Nígbà tí ó ti sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún wọn tan, àwọn Júù lọ, wọ́n bá ara wọn jíyàn púpọ̀.”

30. Pọ́ọ̀lù sì gbé ilé àgbàwọ̀ rẹ̀ lọ́dún méjì gbáko, ó sì ń gbà gbogbo àwọn tí ó wọlé tọ̀ ọ́ wá.

31. Ó ń wàásù ìjọba Ọlọ́run, ó ń fi ìgboyà kọ́ni ní àwọn ohun tí i ṣe ti Jésù Kírísítì Olúwa, ẹnìkan kò dá a lẹ́kun.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 28