Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 26:26-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

26. Nítorí ọba mọ̀ gbogbo nǹkan wọ̀nyí, níwájú ẹni tí èmi ń ṣọ̀rọ̀ ni àìbẹ̀rù: nítorí mo gbàgbọ́ pé ọ̀kan nínú nǹkan wọ̀nyí kò pamọ́ fún un, nítorí tí a kò ṣe nǹkan yìí ní ìkọ̀kọ̀.

27. Àgírípà ọba, ìwọ gba àwọn wòlíì gbọ́ bí? Èmi mọ̀ pé ìwọ gbàgbọ́.”

28. Àgírípà sì wí fún Pọ́ọ̀lù pé, “Ǹjẹ́ ìwọ ró pé ìwọ́ fi àkókò díẹ̀ yìí sọ mí di Kírísítìẹ́nì?”

29. Pọ́ọ̀lù sì dáhùn wí pé, “Ní àkókò kúkúrú tàbí gígùn: mo gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kí ó má ṣe ìwọ nìkan, ṣùgbọ́n kí gbogbo àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ mi lónìí pẹ̀lú lè di irú ènìyàn tí èmi jẹ́ láìsí ẹ̀wọ̀n wọ̀nyí.”

30. Nígbà tí ó sì sọ nǹkan wọ̀nyí tan, ọba dìde, àti baálẹ̀, àti Béníkè, àti àwọn tí o bá wọn jokòó;

31. Nígbà tí wọn wọ yẹ̀wù lọ, wọn bá ara wọn jíròrò, wọ́n sọ pé, “Ọkùnrin yìí kò ṣe nǹkan kan tí ó yẹ sí ikú tàbí sì ẹ̀wọ̀n.”

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 26