Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 25:9-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Ṣùgbọ́n Fẹ́sítúsì ń fẹ́ láti ní ojúrere lọ́dọ̀ àwọn Júù, ó sì dá Pọ́ọ̀lù lóhùn, wí pe, “Ìwọ ń fẹ́ gòkè lọ sì Jerúsálémù, kí a sì ṣe ẹjọ́ nǹkan wọ̀nyí níbẹ̀ níwájú mi bí?”

10. Pọ́ọ̀lù sì wí pé, “Mo dúró níwájú ìtẹ́-ìdájọ́ Késárì níbi tí ó yẹ kí a ṣe ẹjọ́ mí: èmi kò ṣẹ àwọn Júù, bí ìwọ pẹ̀lú ti mọ̀ dájú.

11. Ǹjẹ́ bí mo bá ṣẹ̀, tí mo sí ṣe ohun kan tí ó yẹ fún ikú, èmi kò kọ̀ láti kú: ṣùgbọn bí kò bá sí otítọ́ kan nínú ẹ̀sùn tí àwọn Júù yìí fi mi sùn sí, ẹnìkan kò lẹ́tọ̀ọ́ láti fà mí lé wọn lọ́wọ́. Mo fí ọ̀ràn mi lọ Késárì.”

12. Lẹ́yìn tí Fẹ́sítúsì ti bá àjọ ìgbìmọ̀ sọ̀rọ̀, ó dáhùn pé, “Ìwọ ti fi ọ̀ràn rẹ lọ Késárì. Ní ọ̀dọ̀ Késárì ni ìwọ ó lọ!”

13. Lẹ́yìn ijọ́ mélòó kan, Àgírípà ọba, àti Béníkè sọ̀kalẹ̀ wá sì Kesaríà láti kí Fẹ́sítúsì.

14. Bí wọ́n sì tí wà níbẹ̀ lọ́jọ́ púpọ̀, Fẹ́sítúsì mú ọ̀ràn Pọ́ọ̀lù wá síwájú ọba, wí pé, “Fẹ́líkísì fi ọkùnrin kan ṣílẹ̀ nínú túbú.

15. Ẹni tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbààgbà àwọn Júù fi sùn nígbà tí mo wà ni Jerúsálémù, wọ́n ń fẹ́ kí èmi ó dá a lẹ́bi ikú.

16. “Àwọn ẹni tí mo sì dá lóhùn pé, kì í ṣe àṣà àwọn ará Róòmù láti dá ẹnìkẹ́ni lẹ́bí, kí ẹni tí a fiṣùn náà tó ko àwọn olùfisùn rẹ̀ lójú, láti lè ri àyè wí tí ẹnu rẹ̀, nítorí ọ̀ràn tí a kà sí i lọ́rùn,

17. Nítorí náà nígbà tí wọ́n jùmọ̀ wá sí ìhín yìí, èmi kò fi ọ̀rọ̀ náà falẹ̀ rara, níjọ́ kéjì mo jókòó lórí ìtẹ́ ìdájọ́, mo sì pàṣẹ pé kí a mú ọkùnrin náà wá.

18. Nígbà tí àwọn olùfiṣùn náa dìde, wọn kò ka ọ̀ràn búburú irú èyí tí mo rò sí i lọ́rùn.

19. Ṣùgbọ́n wọ́n ní ọ̀ràn kan sí i, ní ti ìsìn wọn, àti ní ti Jésù kan tí o tí kú, tí Pọ́ọ̀lù tẹnumọ́ pé ó wà láàyè.

20. Bí èmi kò sì tí mọ̀ bí a tí ń se ìwàdìí nǹkan wọ̀nyí, mo bí i lere pé ṣe ó ń fẹ́ lọ sì Jerúsálémù, kí a sì ṣe ẹjọ́ nǹkan wọ̀nyí níbẹ̀.

21. Ṣùgbọ̀n nígbà tí Pọ́ọ̀lù fi ọ̀ràn rẹ lọ Ọ̀gọ́sítù, pé kí a pa òun mọ́ fún ìdájọ́ rẹ̀, mo pàṣẹ pé kí a pa á mọ́ títí èmi o fi lè rán an lọ sọ́dọ̀ Késárì.”

22. Àgírípà sí wí fún Fésítúsì pé, “Èmi pẹ̀lú fẹ́ láti gbọ ọ̀rọ̀ ọkùnrin náà tìkááramì,” Ó sì wí pé, “Ní ọ̀la ìwọ ó gbọ́ ọ.”

23. Ní ọjọ́ kejì, tí Àgírípà àti Báníkè wọ ilé ẹjọ́ ti àwọn ti ẹ̀sọ́ púpọ̀ pẹ̀lú àwọn olórí ogun àti àwọn ènìyàn ńlá ní ìlú, Fẹ́sítúsì pàṣẹ, wọ́n sì mú Pọ́ọ̀lù jáde.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 25