Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 25:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Lẹ́yìn ọjọ́ méta tí ó dé sí ilẹ̀ náà, Fésítúsì gòkè láti Kesaríà lọ sì Jerúsálémù,

2. ní ibi tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn ènìyàn pàtàkì nínú àwọn Júù ti gbé ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Pọ́ọ̀lù wá síwájú rẹ̀.

3. Wọ́n tọrọ lọ́wọ́ Fẹ́sítúsì, kí ó bá le se ojúrere fuń wọn, kí ó bá à lè jẹ́ kí wọn mú Pọ́ọ̀lù wá sí Jerúsálémù, wọn ń gbìmọ̀ láti dènà dè é, kí wọn sì pa á ní ọ̀nà.

4. Ṣùgbọ́n Fẹ́sítúsì dáhùn pé, “A pa Pọ́ọ̀lù mọ́ ní Kesaríà, àti pé òun tíkara òun ń múra àti padà lọ ní lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí.

5. Ẹ jẹ́ kí díẹ̀ nínú àwọn olórí yín bá mi sọ̀kalẹ̀ lọ láti fi ìdí ẹ̀sùn tí ẹ fi sun ọkùnrin náà múlẹ̀ níbẹ̀, bí ó bá ní ohun búburú kan tí ó wà lọ́wọ́ rẹ̀.”

6. Lẹ́yìn tí ó sì ti gbé níwọ̀n ọjọ́ mẹ́jọ tàbí mẹ́wàá pẹ̀lú wọn, ó ṣọ̀kalẹ̀ lọ sì Kesaríà, ni ọjọ́ kéjì ó jókòó lórí ìtẹ́ ìdájọ́, ó sì pàṣẹ pé ki a mú Pọ́ọ̀lù wá síwájú òun.

7. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù sì dé, àwọn Júù tí o tí Jerúsálémù ṣọ̀kalẹ̀ wá dúró yì í ká, wọ́n ǹ ka ọ̀ràn púpọ̀ tí ó sì burú sí Pọ́ọ̀lù lọ́rùn, tí wọn kò lè làdí rẹ̀.

8. Pọ́ọ̀lù si wí tí ẹnu rẹ̀ pé, “Èmi kò ṣẹ ẹ̀ṣẹ̀kẹ́ṣẹ̀ kan sì òfin àwọn Júù, tàbí tẹ́ḿpílì, tàbí sí Késárì”

9. Ṣùgbọ́n Fẹ́sítúsì ń fẹ́ láti ní ojúrere lọ́dọ̀ àwọn Júù, ó sì dá Pọ́ọ̀lù lóhùn, wí pe, “Ìwọ ń fẹ́ gòkè lọ sì Jerúsálémù, kí a sì ṣe ẹjọ́ nǹkan wọ̀nyí níbẹ̀ níwájú mi bí?”

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 25