Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 23:32-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

32. Ní ọjọ́ kejì wọ́n sì fi àwọn ẹlẹ́ṣin sílẹ̀ láti máa bá a lọ, àwọn sì padà wá sínú àgọ́ àwọn ológun.

33. Nígbà tí wọ́n dé Kesaríà, tí wọ́n sí fi ìwé fún baalẹ́, wọ́n mú Pọ́ọ̀lù pẹ̀lú wá ṣíwájú rẹ̀.

34. Nígbà tí ó sì ti ka ìwé náà, ó bèèrè pé agbégbé ìlú wo ni tirẹ̀. Nígbà tí ó sì gbọ́ pé ará Kílíkíà ni;

35. Ó ní, “Èmi yóò gbọ ẹjọ́ rẹ, nígbà tí àwọn olùfiṣùn rẹ pẹ̀lú bá dé.” Ó sì paṣẹ pé kí wọn pa Pọ́ọ̀lù mọ́ ní abẹ́ àmójútó àwọn olùsọ́ ní gbọ̀ngán-ídájọ́ ààfin Hẹ́rọ́dù.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 23