Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 22:2-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Nígbà tí wọ́n sì gbọ́ pé ó ń bá wọn sọ̀rọ̀ ni èdè Árámáíkì, wọ́n túbọ̀ dákẹ́ jẹ́ẹ́.Nígbà náà ni ó wí pé:

3. “Júù ni èmi í ṣe, a bí mi ni Tásọ́sì ìlú kan ní Kílíkíà, ṣùgbọ́n tí a tọ́ mi dàgbà ni ìlú yìí. Ní abẹ́ ẹsẹ̀ Gàmálíẹ́lì ni a sì gbé kọ́ mi ní òfin àwọn baba wa, tí mo sì jẹ́ onítara fún Ọlọ́run àní gẹ́gẹ́ bí gbogbo yin tí rí ni òní.

4. Mo sì ṣe inúnibíni sí àwọn ènìyàn tí ń tọ ọ̀nà yìí dé ojú ikú wọn, mo dè tọkùnrin àtobìnrin wọ́n, mo sì fi wọ́n sínú túbú,

5. àní bí olórí àlùfáà pẹ̀lú gbogbo àjọ àwọn alàgbà tí lè jẹ́ mi ní ẹ̀rí. Mo tilẹ̀ gba ìwé àṣẹ lọ́wọ́ wọn lọ sọ́dọ̀ àwọn arakùnrin wọn ní Dámásíkù láti mú àwọn tí ó wà níbẹ̀ ní dídè wá sí Jerúsálémù, láti jẹ wọ́n níyà.

6. “Bí èmi tí súnmọ́ etí Dámásíkù níwọ̀n ọjọ́kanrí, lójijì ìmọ́lẹ̀ ńlá láti ọ̀run wá mọ́lẹ̀ yí mi ká.

7. Mo sì subú lulẹ̀, mo sì gbọ́ ohùn kan tí ó wí fún mi pé, ‘Ṣọ́ọ̀lù, Ṣọ́ọ̀lù èé ṣe tí ìwọ fi ń ṣe inúnibíni sí mi?’

8. “Mo sì béèrè pé, ‘Ta ni ìwọ́, Olúwa?’“Ó sì dá mi lóhùn pé, ‘Èmi ni Jésù tí Násárétì, ẹni tí ìwọ́ ń ṣe inúnibíni sí.’

9. Àwọn tí ó sì wà pẹ̀lú mi rí ìmọ́lẹ̀ náà nítòótọ́, ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́ ohùn ẹni tí ń bá mi sọ̀rọ̀.

10. “Mo sí béèrè pé, ‘Kín ni kí èmí kí ó ṣe, Olúwa?’“Olúwa sì wí fún mi pé, ‘Dìde, kí o sì lọ sí Dámásíkù; níbẹ̀ ni a ó sì ti sọ ohun gbogbo fún ọ tí a yàn fún ọ láti ṣe.’

11. Àwọn tí ó sì wà pẹ̀lú mi fà mí lọ́wọ́ wọ Dámásíkù lọ nítorí tí èmi kò lè ríran nítorí ìtànṣán ìmọ́lẹ̀ náà ti fọ́ mi ní ojú.

12. “Ọkùnrin kan tí a ń pè ní Ananáyà tọ̀ mí wá, ẹni tó jẹ́ olùfọkànṣìn ti òfin, tí ó sì lórúkọ rere lọ́dọ̀ gbogbo àwọn Júù tí ó ń gbé ibẹ̀.

13. Ó sì dúró tì mí, ó sì wí fún mi pé, ‘Arákùnrin Ṣọ́ọ̀lù, gba ìríran!’ Ní ẹsẹ̀ kan náà, mo sì sí ojú sí òkè mo sì lè rí i.

14. “Nígbà náà ni ó wí pé: ‘Ọlọ́run àwọn baba wa ti yàn ọ́ láti mọ ìfẹ́ rẹ̀, àti láti ri Ẹni Òdodo náà, àti láti gbọ́ ọ̀rọ̀ láti ẹnu rẹ̀.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 22