Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 21:18-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Ní ijọ́ kejì, a bá Pọ́ọ̀lù lọ sọ́dọ̀ Jákọ́bù; gbogbo àwọn alàgbà sì wà níbẹ̀.

19. Nígbà tí ó sì kí wọn tan, ó ròyìn lẹsẹẹsẹ ohun gbogbo tí Ọlọ́run ṣe láàrin àwọn aláìkọlà nípa iṣẹ́-ìránṣẹ́ rẹ̀.

20. Nígbà tí wọ́n sì gbọ́, wọ́n yin Ọlọ́run lógo, wọ́n sì wí fún un pé, “Arákùnrin, ìwọ rí iye ẹgbẹẹgbẹ̀rún nínú àwọn Júù tí ó gbàgbọ́, gbogbo wọn ni ó sì ní ìtara fún òfin.

21. Wọ́n sì ti ròyìn rẹ̀ fún wọn pé, ìwọ ń kọ́ gbogbo àwọn Júù tí ó wà láàrin àwọn aláìkọlà pé, kí wọn kọ Mósè sílẹ̀, ó ń wí fún wọn pé kí wọn má ṣe kọ àwọn ọmọ wọn ní ilà mọ́, kí wọn má sì ṣe rìn gẹ́gẹ́ bí àṣà wọn.

22. Ǹjẹ́ èwo ni ṣíṣe? Ìjọ kò lè ṣàìmá pejọ pọ̀: dájúdájú wọn óò gbọ́ pé, ìwọ dé.

23. Ǹjẹ́ èyí tí àwa ó wí fún ọ yìí ni kí o ṣe: Àwa ni ọkùnrin mẹ́rin tí wọ́n wà lábẹ́ ẹ̀jẹ́;

24. Àwọn ni kí ìwọ mú, ki o sì ṣe ìwẹ̀nùmọ́ pẹ̀lú wọn kí ó sì san owó láti fá irun orí wọn: gbogbo ènìyàn yóò sì mọ̀ pé, kò sì òtítọ́ kan nínú ohun tí wọ́n gbọ́ sí ọ; àti pé, ìwọ tìkararẹ ń rìn dédé, ìwọ sì ń pa òfin Mósè mọ́.

25. Ṣùgbọ́n ní ti àwọn aláìkọlà tí ó gbàgbọ́, àwa tí kọ̀wé, a sì ti pinnu rẹ̀ pé, kí wọn pa ara wọn mọ́ kúrò nínú ohun tí a fi rúbọ sí òrìṣà, àti ẹ̀jẹ̀ àti ohun ìlọ́lọ́rùn pa, àti àgbérè.”

26. Nígbà náà ni Pọ́ọ̀lù mú àwọn ọkùnrin náà; ní ijọ́ kéjì ó ṣe ìwẹ̀nùmọ́ pẹ̀lú wọn, ó sì wọ inú tẹ́ḿpílì lọ, láti sọ ìgbà tí ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́ náà yóò pé tí a ó sì fi ọrẹ lélẹ̀ fún olukùlùkù wọn.

27. Nígbà tí ọjọ́ méje sì fẹ́rẹ̀ pé, tí àwọn Júù tí ó ti Éṣíà wá rí i ni tẹ́ḿpílì, wọ́n rú gbogbo àwọn ènìyàn sókè, wọ́n nawọ́ mú un.

28. Wọ́n ń kígbe wí pé, “Ẹ̀yin ènìyàn Ísírẹ́lì, ẹ gbà wá: Èyí ni ọkùnrin náà tí ń kọ́ gbogbo ènìyàn níbi gbogbo lòdì sí àwọn èniyan, àti sí òfin, àti sí ibí yìí: àti pẹ́lú ó sì mú àwọn ará Gíríkì wá sí tẹ́ḿpílì, ó sì tí ba ibi mímọ́ yìí jẹ́.”

29. Nítorí wọ́n tí rí Tírófímù ará Éfésù pẹ̀lú rẹ̀ ní ìlú, ẹni tí wọ́n ṣe bí Pọ́ọ̀lù mú wá sínú tẹ́ḿpílì.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 21