Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 20:28-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

28. Ẹ kíyèsára yin, àti sí gbogbo agbo tí Ẹ̀mí Mímọ́ fi yín ṣe alábòójútó rẹ̀, láti máa tọ́jú ìjọ Ọlọ́run, tí ó tí fi ẹ̀jẹ̀ (ọmọ) rẹ̀ rà.

29. Nítorí tí èmi mọ̀ pé, lẹ́yìn lílọ̀ mi, ìkookò búburú yóò wọ àárin yín, yóò sì tú agbo ká.

30. Láàrin ẹ̀yin tìkárayín ni àwọn ènìyàn yóò sì dìde, tí wọn yóò máa sọ̀rọ̀-òdì, láti fa àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sẹ́yìn wọn.

31. Nítorí náà ẹ máa sọ́ra, ki ẹ sì máa rántí pé, fún ọdún mẹ́ta, èmi kò dẹ́kun láti máa fi omijé kìlọ̀ fún olúkúlùkù ní ọ̀sán àti ní òru.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 20