Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 20:16-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Pọ́ọ̀lù ṣa ti pinnu rẹ̀ láti bá ọkọ̀-ojú omi kọjá ṣí Éféṣù, nítorí ki ó má baà lo àkókò kankan ni Éṣíà: nítorí tí ó ń yára bí yóò ṣe ṣééṣe fún un láti wà ní Jerúsálémù lọ́jọ́ Pẹ́ńtíkọ́sítì.

17. Ní àti Mílétù ni Pọ́ọ̀lù ti ránṣẹ́ sí Éféṣù, láti pé àwọn alàgbà ìjọ wá ṣọ́dọ̀ rẹ̀.

18. Nígbà tí wọ́n sì dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin tìkarayín mọ̀, láti ọjọ́ kìn-ín-ní tí mo tí dé Éṣíà, bí mo ti bá yín gbé, ní gbogbo àkókò náà.

19. Bí mo ti ń fi ìrẹ̀lẹ̀ inú gbogbo sin Olúwa, àti omijé púpọ̀, pẹ̀lú ìdánwò, tí ó bá mi, nípa rìkíṣí àwọn Júù:

20. Bí èmí kò ti fà ṣẹ́yìn láti sọ ohunkohun tí ó ṣàǹfàànì fún un yín, àti láti máa kọ́ ọ yín ní gbangba àti láti ilé dé ilé.

21. Tí mo ń sọ fún àwọn Júù, àti fún àwọn Gíríkì pẹ̀lú, ní ti ìrònúpìwàdà sí Ọlọ́run, àti ti ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kírísítì Olúwa wa.

22. “Ǹjẹ́ nsṣinsìn yìí, wò ó, ẹ̀mí mi ń fà sì Jerúsálémù, láìmọ̀ ohun tí yóò bá mi níbẹ̀:

23. Bí kò ṣe bí Ẹ̀mí Mímọ́ tí ń sọ ní ìlú gbogbo pé, ìdè àti ìyà ń bẹ fún mi.

24. Ṣùgbọn èmi kò ka ọkàn mi sí nǹkan rárá bi ohun tí ó sọ̀wọ́n fún mi àti iṣẹ́-ìránṣẹ́ tí mo tí gbà lọ́dọ̀ Jésù Olúwa, láti máa ròyìn ìyìn rere oore-ọ̀fẹ́ Ọ̀lọ́run.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 20