Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 2:24-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

24. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run jí díde kúrò nínú òkú, gbà á kúrò nínú ìrora ikú: nítorí tí kò ṣe é ṣe fún ikú láti dì í mú.

25. Dáfídì tí wí nípa tirẹ̀ pé:“ ‘Mo rí Olúwa nígbà gbogbo niwájú mí,nítorí tí ó ń bẹ lọ́wọ́ ọ̀tún mi,A kì ó ṣí mi ní ipò.

26. Nítorí náà inú mi dùn, ahọ́n mi sì yọ̀:pẹ̀lúpẹ̀lú ara mi yóò sì sinmi ní ìrètí.

27. Nítorí tí ìwọ kí yóò fi ọkàn mi sílẹ̀ ni isà-òkú,bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kí yóò jẹ́ kí Ẹni-Mímọ́ rẹ rí ìdíbàjẹ́.

28. Ìwọ mú mi mọ ọ̀nà ìyè,ìwọ yóò mú mi kún fún ayọ̀ ni iwájú rẹ.’

29. “Ará, èmí lè sọ fún yin pẹ́lú ìgboyà pé ní ti Dáfídì baba ńlá kú, a sì sin ín, ibojì rẹ̀ sì ń bẹ lọ́dọ̀ wa títí di òní yìí.

30. Ṣùgbọ́n ó jẹ́ wòlíì, àti bí ó mọ́ pé, Ọlọ́run ti ṣe ìlérí fún òun nínú ìbúra pé nínú irú-ọmọ inú rẹ̀, òun yóò mú ọ̀kan jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀.

31. Ní rírí èyí tẹ́lẹ̀, ó sọ ti àjíǹde Kírísítì, pé a kò fi ọkan rẹ̀ sílẹ̀ ni isà-òkú, bẹ́ẹ̀ ni ara rẹ̀ kò rí ìdíbàjẹ́.

32. Jésù náà yìí ni Ọlọ́run ti jí díde sí ìyè, àwa pẹ̀lú sì jẹ́rìí sí èyí.

33. A ti gbé ga sí ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run, ó ti gba ìlérí Ẹ̀mí Mímọ́ láti ọ̀dọ̀ Baba, ó tu èyí tí ẹ̀yin rí àti gbọ́ nísinsìyìí sítá.

34. Nítorí Dáfídì kò gókè lọ sí ọ̀run ṣùgbọ́n òun tìkárarẹ̀ wí pé,“ ‘Olúwa wí fún Olúwa mi pé:“Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi

35. títí èmi yóò fi sọ àwọn ọ̀ta rẹdí àpótí ìtìsẹ̀ fún ẹsẹ̀ rẹ.” ’

36. “Ǹjẹ́ kí gbogbo ilé Ísírẹ́lì mọ̀ dájúdájú pé: Ọlọ́run ti fi Jésù náà, ti ẹ̀yin kàn mọ́ àgbélébùú, se Olúwa àti Kírísítì.”

37. Nígbà tí wọ́n sì gbọ́, ọkàn wọn gbọgbẹ́, wọn sì wí fún Pétérù àti àwọn àpósítélì yòókù pé, “Ará, kín ni àwa yóò ṣe”

38. Pétérù sì wí fún wọn pé, “Ẹ ronúpìwàdà, kí a sì bamitíìsì olúkúkùkù yín ní orúkọ Jésù Kírísítì fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ yín. Ẹ̀yin yóò sì gba ẹbun Ẹ̀mí Mímọ́

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 2