Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 2:20-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. A yóò sọ òòrùn di òkùnkùn,àti òṣùpá di ẹ̀jẹ̀,kí ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ ológo Olúwa tó dé.

21. Yóò sì ṣe pé ẹnikẹ́ni tí ó bá peorúkọ Olúwa ni a ó gbàlà.’

22. “Ẹ̀yin ènìyàn Ísírẹ́lì, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí; Jésù tí Násárẹ́tì, ọkùnrin tí a mọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá nípa iṣẹ́ agbára àti tí ìyanu, àti àmì ti Ọlọ́run ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe láàrin yín, bí ẹ̀yin tíkárayín ti mọ̀ pẹ̀lú.

23. Ẹni tí a ti fi lé yín lọ́wọ́ nípa ìpinnu ìmọ̀ àti ìmọ̀tẹ́lẹ̀ Ọlọ́run; àti ẹ̀yin pẹ̀lú, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú kàn mọ́ àgbélébùú, tí a sì pa á.

24. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run jí díde kúrò nínú òkú, gbà á kúrò nínú ìrora ikú: nítorí tí kò ṣe é ṣe fún ikú láti dì í mú.

25. Dáfídì tí wí nípa tirẹ̀ pé:“ ‘Mo rí Olúwa nígbà gbogbo niwájú mí,nítorí tí ó ń bẹ lọ́wọ́ ọ̀tún mi,A kì ó ṣí mi ní ipò.

26. Nítorí náà inú mi dùn, ahọ́n mi sì yọ̀:pẹ̀lúpẹ̀lú ara mi yóò sì sinmi ní ìrètí.

27. Nítorí tí ìwọ kí yóò fi ọkàn mi sílẹ̀ ni isà-òkú,bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kí yóò jẹ́ kí Ẹni-Mímọ́ rẹ rí ìdíbàjẹ́.

28. Ìwọ mú mi mọ ọ̀nà ìyè,ìwọ yóò mú mi kún fún ayọ̀ ni iwájú rẹ.’

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 2