Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 19:7-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Iye àwọn ọkùnrin náà gbogbo tó méjìlá.

8. Nígbà tí ó sì wọ inú Sínágọ́gù lọ ó fi ìgboyà sọ̀rọ̀ ni oṣù mẹ́ta, ó ń fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀, ó sì ń yí wọn lọ́kàn padà sí nǹkan tí i ṣe tí ìjọba Ọlọ́run.

9. Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkàn àwọn mìíràn nínú wọn di líle, tí wọn kò sì gbàgbọ́, tí wọn ń sọ̀rọ̀ ibi sí ọ̀nà náà níwájú ìjọ ènìyàn, ó lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó sì ya àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sọ́tọ̀, ó sì ń sọ àsọyé lójoójúmọ́ ni ilé-ìwé Tíráńnù.

10. Èyí n lọ bẹ́ẹ̀ fún ìwọ̀n ọdún méjì; tóbẹ́ẹ̀ tí gbogbo àwọn tí ń gbé Éṣíà gbọ́ ọ̀rọ̀ Jésù Olúwa, àti àwọn Júù àti àwọn Gíríkì.

11. Ọlọ́run sì tí ọwọ́ Pọ́ọ̀lù ṣe àwọn àkànṣe iṣẹ́ ìyànu,

12. Tóbẹ́ẹ̀ tí a fi ń mú aṣọ àti ìbàǹtẹ́ ara rẹ̀ tọ àwọn ọlọ́kùnrùn lọ, àrùn sì fi wọ́n sílẹ̀, àwọn ẹ̀mí búburú sì jáde kúrò lára wọn.

13. Ṣùgbọ́n àwọn Júù kan alárìnkiri, alẹ́mìí-èṣù jáde, bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ ni àdábọwọ́ ara wọn, láti pé orúkọ Jésù Olúwa sí àwọn tí ó ni ẹ̀mí búburú, wí pé, “Àwa fi orúkọ Jésù tí Pọ́ọ̀lù ń wàásù fi yín bú.”

14. Àwọn méje kan sì wà, tí wọn ń ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ ẹnìkan tí a ń pè ni Síkẹ́fà, Júù, tí í ṣe olórí àlùfáà gíga.

15. Ẹmí búburú náà sì dáhùn, ó ní “Jéù èmi mọ̀ ọ́n, mo sì mọ Pọ́ọ̀lù pẹ̀lú, ṣùgbọ́n ta ni ẹ̀yin?”

16. Nígbà tí ọkùnrin tí ẹ̀mí búburú náà wà lára rẹ̀ sì fò mọ́ wọn, ó pá kúúrù mọ́ wọn, ó sì borí wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sá jáde kúrò ní ilé náà ní ìhòòhò pẹ̀lú ni ìfarapa.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 19