Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 19:22-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Nígbà tí ó sì tí rán méjì nínú àwọn tí ń ṣe ìránṣẹ́ fún un lọ ṣí Makedóníà, Tímótíù àti Érásítù, òun tìkararẹ̀ dúró díẹ̀ ní ilẹ̀ Éṣíà.

23. Ní àkókò náà ìrúkèrúdò díẹ̀ kan wà nítorí ọ̀nà náà.

24. Nítorí ọkùnrin kan tí a ń pè ní Démétíríù, alágbẹ̀dẹ fàdákà, tí o máa ń fi fàdákà ṣe ilé-òrìṣà fún Dáyánà, ó mú ère tí kò mọ níwọ̀n wá fún àwọn oníṣọ̀nà;

25. Nígbà tí ó pè wọ́n jọ, àti irú àwọn oníṣẹ́-ọ̀nà bẹ́ẹ̀, ó ní, “Alàgbà, ẹ̀yin mọ̀ pé nipa iṣẹ́-ọnà yìí ni àwa fi ní ọrọ̀ wa.

26. Ẹ̀yin sì rí i, ẹ sì gbọ́ pé, kì í ṣe ni Éfésù nìkanṣoṣo ni, ṣùgbọ́n ó fẹrẹ jẹ́ gbogbo Éṣíà, ni Pọ́ọ̀lù yìí ń yí ọ̀pọ̀ ènìyàn lọ́kàn padà, tí ó sì ń dárí wọn wí pé, ohun tí a fi ọwọ́ ṣe, kì í ṣe Ọlọ́run.

27. Kì í sì ṣe pé kìkí iṣẹ́-ọnà wa yìí ni ó wà nínú ewu dídí aṣán; ṣùgbọ́n ilé Dáyánà òrìṣà ńlá yóò di gígàn pẹ̀lú, àti gbogbo ọlá-ńlá rẹ̀ yóò sì run, ẹni tí gbogbo Éṣíà àti gbogbo ayé ń bọ.”

28. Nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, wọ́n kún fún ìbínú, wọ́n kígbe, wí pé, “Òrìṣà ńlá ni Dáyánà ti ará Éfésù!”

29. Gbogbo ìlú náà sì kún fún ìrúkèrúdò: wọ́n sì fi ipa fa Gáíù àti Árísítaríkù ara Makedóníà lọ pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́gbẹ́ Pọ́ọ̀lù nínú ìrìn-àjò.

30. Nígbà ti Pọ́ọ̀lù sì ń fẹ́ wọ àárin àwọn ènìyàn lọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kọ̀ fún un.

31. Àwọn olórí kan ara Éṣíà, tí i ṣe ọ̀rẹ́ rẹ̀, ránṣẹ́ sí i, wọ́n bẹ̀ ẹ́ pé, kí ó má ṣe fi ara rẹ̀ wéwu nínú ilé ibi-ìṣeré náà.

32. Ǹjẹ́ àwọn kan ń wí ohun kan, àwọn mìíràn ń wí òmíran: nítorí àjọ di rúdurùdu; ọ̀pọ̀ ènìyàn ni kò sì mọ̀ ìdí ohun tí wọ́n tilẹ̀ fi péjọ pọ̀.

33. Àwọn kan nínú àwujọ ń gún Alekisáńdérù, tí àwọn Júù tì síwájú, ní kẹ́ṣẹ́ láti ṣọ̀rọ̀ Alekisáńdérù sì juwọ́ sì wọn, òun ìbá sì wí ti ẹnu rẹ̀ fún àwọn ènìyàn.

34. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n mọ̀ pé Júù ni, gbogbo wọn, ni ohùn kan, bẹ̀rẹ̀ ṣí kígbe fún bi wákàtí méjì pé, “Òrìṣà ńlá ni Dáyánà tí ará Éfésù!”

35. Nígbà tí akọ̀wé ìlú sì mú kí ìjọ ènìyàn dákẹ́, ó ní, “Ẹ̀yin ará Éfésù, ta ni ẹni tí ó wà tí kò mọ̀ pé, ìlú ará Éfésù ní í ṣe olùsìn Dáyánà òrìṣà ńlá, àti tí ère tí ó ti ọ̀dọ̀ Júpítérì bọ́ sílẹ̀?

36. Ǹjẹ́ bi a kò tilẹ̀ sọ̀rọ̀-òdì sí nǹkan wọ̀nyí, ó yẹ kí ẹ dákẹ́, kí ẹ̀yin má ṣe fi ìwara ṣe ohunkohun.

37. Nítorí ti ẹ̀yin mú àwọn ọkùnrin wọ̀nyí wá, wọn kò ja ilé òrìṣà lólè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ṣọ̀rọ̀-òdì ṣí òrìṣà wa.

38. Ǹjẹ́ nítorí náà tí Démétíríù, àti àwọn oníṣẹ́-ọnà tí o wà pẹ̀lú rẹ̀ bá ní gbólóhùn-asọ̀ kan sí ẹnìkẹ́ni, ilé-ẹjọ́ ṣí sílẹ̀, àwọn onídájọ́ sì ń bẹ: jẹ́ kí wọn lọ fi ara wọn sùn.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 19