Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 19:14-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Àwọn méje kan sì wà, tí wọn ń ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ ẹnìkan tí a ń pè ni Síkẹ́fà, Júù, tí í ṣe olórí àlùfáà gíga.

15. Ẹmí búburú náà sì dáhùn, ó ní “Jéù èmi mọ̀ ọ́n, mo sì mọ Pọ́ọ̀lù pẹ̀lú, ṣùgbọ́n ta ni ẹ̀yin?”

16. Nígbà tí ọkùnrin tí ẹ̀mí búburú náà wà lára rẹ̀ sì fò mọ́ wọn, ó pá kúúrù mọ́ wọn, ó sì borí wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sá jáde kúrò ní ilé náà ní ìhòòhò pẹ̀lú ni ìfarapa.

17. Ìròyìn yìí sì di mímọ̀ fún gbogbo àwọn Júù àti àwọn ará Gíríkì pẹ̀lú tí ó ṣe àtìpó ní Éfésù; ẹ̀rù sì ba gbogbo wọn, a sì gbé orúkọ Jésù Olúwa ga.

18. Ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n gbàgbọ́ sì wá, wọ́n jẹ́wọ́, wọ́n sì fi iṣẹ́ wọn hàn.

19. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn tí ń se alálùpàyídà ni ó kó ìwé wọn jọ, wọ́n dáná sun wọ́n lójú gbogbo ènìyàn: wọ́n sì sirò iye wọn, wọ́n sì rí i, ó jẹ́ ẹgbàámẹ́ẹ̀dọ́gbọ́n ìwọ̀n fàdákà.

20. Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ Olúwa gbérú tí o sí gbilẹ̀ si í gidigidi.

21. Ǹjẹ́ bí nǹkan wọ̀nyí tí parí tan, Pọ́ọ̀lù pínnu nínú ẹ̀mí rẹ̀ pé, nígbà tí òun bá kọjá ní Makedóníà àti Ákáyà, òun ó lọ sí Jerúsálémù, ó wí pé, “Lẹ́yìn ìgbà tí mo bá dé ibẹ̀, èmi kò lè ṣàì má dé Róòmù pẹ̀lú.”

22. Nígbà tí ó sì tí rán méjì nínú àwọn tí ń ṣe ìránṣẹ́ fún un lọ ṣí Makedóníà, Tímótíù àti Érásítù, òun tìkararẹ̀ dúró díẹ̀ ní ilẹ̀ Éṣíà.

23. Ní àkókò náà ìrúkèrúdò díẹ̀ kan wà nítorí ọ̀nà náà.

24. Nítorí ọkùnrin kan tí a ń pè ní Démétíríù, alágbẹ̀dẹ fàdákà, tí o máa ń fi fàdákà ṣe ilé-òrìṣà fún Dáyánà, ó mú ère tí kò mọ níwọ̀n wá fún àwọn oníṣọ̀nà;

25. Nígbà tí ó pè wọ́n jọ, àti irú àwọn oníṣẹ́-ọ̀nà bẹ́ẹ̀, ó ní, “Alàgbà, ẹ̀yin mọ̀ pé nipa iṣẹ́-ọnà yìí ni àwa fi ní ọrọ̀ wa.

26. Ẹ̀yin sì rí i, ẹ sì gbọ́ pé, kì í ṣe ni Éfésù nìkanṣoṣo ni, ṣùgbọ́n ó fẹrẹ jẹ́ gbogbo Éṣíà, ni Pọ́ọ̀lù yìí ń yí ọ̀pọ̀ ènìyàn lọ́kàn padà, tí ó sì ń dárí wọn wí pé, ohun tí a fi ọwọ́ ṣe, kì í ṣe Ọlọ́run.

27. Kì í sì ṣe pé kìkí iṣẹ́-ọnà wa yìí ni ó wà nínú ewu dídí aṣán; ṣùgbọ́n ilé Dáyánà òrìṣà ńlá yóò di gígàn pẹ̀lú, àti gbogbo ọlá-ńlá rẹ̀ yóò sì run, ẹni tí gbogbo Éṣíà àti gbogbo ayé ń bọ.”

28. Nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, wọ́n kún fún ìbínú, wọ́n kígbe, wí pé, “Òrìṣà ńlá ni Dáyánà ti ará Éfésù!”

29. Gbogbo ìlú náà sì kún fún ìrúkèrúdò: wọ́n sì fi ipa fa Gáíù àti Árísítaríkù ara Makedóníà lọ pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́gbẹ́ Pọ́ọ̀lù nínú ìrìn-àjò.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 19