Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 19:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà ti Àpólò wà ni Kọ́ríńtì, ti Pọ́ọ̀lù kọjá lọ sí apá òkè-ìlú, ó sì wá ṣí Éfésù: o sì rí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kan;

2. Ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ha gba Ẹ̀mi Mímọ́ náà nígbà tí ẹ̀yin gbàgbọ́?”Wọ́n sì wí fún un pé, “Àwa kò gbọ́ rárá pé Ẹ̀mí Mímọ́ kan wà.”

3. Ó sì wí pé, “Ǹjẹ́ irú bamítíìsímù wo ni a bamitíìsímù yín sí?”Wọ́n sì wí pé, “Sí bamitíìsímù tí Jòhánù.”

4. Pọ́ọ̀lù sí wí pé, “Nítọ̀ọ́tọ́, ní Jòhánù fi bamitíìsímù tí ìrònúpìwàdà bamitíìsímù, ó ń wí fún àwọn ènìyàn pé, kí wọ́n gba ẹni tí ń bọ̀ lẹ́yìn òun gbọ́, èyí sì ni Kírísítì Jésù.”

5. Nígbà tí wọ́n sì gbọ́, a bamitíìsímù wọn lórúkọ Jéṣù Olúwa.

6. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù sì gbé ọwọ́ lé wọn, Ẹ̀mí Mímọ́ sì bà lé wọn: wọ́n sì ń fọ́ èdè mìíràn, wọ́n sì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀.

7. Iye àwọn ọkùnrin náà gbogbo tó méjìlá.

8. Nígbà tí ó sì wọ inú Sínágọ́gù lọ ó fi ìgboyà sọ̀rọ̀ ni oṣù mẹ́ta, ó ń fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀, ó sì ń yí wọn lọ́kàn padà sí nǹkan tí i ṣe tí ìjọba Ọlọ́run.

9. Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkàn àwọn mìíràn nínú wọn di líle, tí wọn kò sì gbàgbọ́, tí wọn ń sọ̀rọ̀ ibi sí ọ̀nà náà níwájú ìjọ ènìyàn, ó lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó sì ya àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sọ́tọ̀, ó sì ń sọ àsọyé lójoójúmọ́ ni ilé-ìwé Tíráńnù.

10. Èyí n lọ bẹ́ẹ̀ fún ìwọ̀n ọdún méjì; tóbẹ́ẹ̀ tí gbogbo àwọn tí ń gbé Éṣíà gbọ́ ọ̀rọ̀ Jésù Olúwa, àti àwọn Júù àti àwọn Gíríkì.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 19