Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 18:14-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń fẹ́ dáhùn, Gálíónì wí fún àwọn Júù pé, “Ìbá ṣe pé ọ̀ràn búburú tàbí tí jàgídíjàgan kan ni, èmi ìbá gbè yín, ẹyin Júù;

15. Ṣùgbọ́n bí ó ti ṣe ọ̀ràn nipa ọ̀rọ̀ àti orúkọ, àti ti òfin yín ni, ki ẹ̀yin bojútó o fúnrará yín; nítorí tí èmi kò fẹ ṣe onídàjọ́ nǹkan báwọ̀nyí.”

16. Ó sì lé wọn kúrò ní ibi ìtẹ́ ìdájọ́.

17. Gbogbo àwọn Gíríkì sì mú Sósìténì, olórí ṣínágógù, wọ́n sì lù ú níwájú ìtẹ́ ìdájọ́. Gálíónì kò sì bìkítà fún nǹkan wọ̀nyí.

18. Pọ́ọ̀lù sì dúró sí i níbẹ̀ lọ́jọ́ púpọ̀, nígbà tí ó sì dágbére fún àwọn arákùnrin, ó bá ọkọ̀-ojúomi lọ si Síríà, àti Pìrìsílà àti Àkúílà pẹ̀lú rẹ̀; ó tí fá orí rẹ̀ ni Kéníkíríà: nítorí tí o tí jẹ́jẹ̀ẹ́.

19. Ó sì sọ̀kalẹ̀ wá sí Éféṣù, ó sì fi wọ́n sílẹ̀ níbẹ̀: ṣùgbọ́n òun tìkararẹ̀ wọ inú Sínágọ́gù lọ, ó sì bá àwọn Júù fí ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀.

20. Nígbà tí wọ́n sì bẹ̀ ẹ́ pé, kí ó bá àwọn jókòó díẹ̀ sí i, ó kọ̀;

21. Ṣùgbọ́n ó dágbére fún wọn, ó sì wí pé, (Èmi kò gbọdọ̀ má ṣe àjọ ọdún tí ń bọ̀ yìí ni Jerúsálémù bí ó tí wù kí ó rí: ṣùgbọ́n) “Èmi ó tún padà tọ̀ yín wá, bí Ọlọ́run bá fẹ́.” Ó sì ṣíkọ̀ láti Éfésù.

22. Nígbà tí ó sì tí gúnlẹ̀ ni Keṣaríà; tí ó gòkè, tí ó sì kí ijọ, ó sọ̀kalẹ̀ lọ sì Áńtíókù.

23. Nígbà tí ó sì gbé ọjọ́ díẹ̀ níbẹ, ó lọ, ó sì kọjá lọ láti Gálátíà àti Fírígíà, ó mú gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn lọ́kàn le.

24. Júù kan sì wà tí a ń pè ni Àpólò, tí a bí ni Alekisáńdíríà, ó wá sí Éféṣù. Ó nì ẹ̀bùn ọ̀rọ̀-sísọ, ó sì mọ ìwé mímọ́ púpọ̀;

25. Ọkùnrin yìí ni a tí kọ́ ní ọ̀nà tí Olúwa; ó sì ṣe ẹni tí ó ní ìtara tí ẹ̀mí, ó ń sọ̀rọ̀ ó sì ń kọ́ni ní àwọn ohun tí i ṣe ti Olúwa dáradára; kìkì bamitíìsímù tí Jòhánù ní ó mọ̀.

26. Ó sì bẹ̀rẹ̀ ṣí fi ìgboyà sọ̀rọ̀ ni Sínágọ́gù: nígbà tí Àkúílà àti Pìrìskílà gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n mú un sọ́dọ̀ wọ́n sì túbọ̀ sọ ọ̀nà Ọlọ́run fún un dájúdájú.

27. Nígbà tí ó sì ń fẹ́ kọjá lọ sì Ákáyà, àwọn arakùnrin gbà á ní ìyànjú, wọ́n sì kọ̀wé sí àwọn ọmọ-ẹ̀hìn kí wọ́n gbà á: nígbà tí ó sì dé, ó ràn àwọn tí ó gbàgbọ́ nípasẹ̀ oore-ọfẹ lọ́wọ́ púpọ̀,

28. Nítorí tí o sọ àsọyé fún àwọn Júù ní gbangba, ó ń fi í hàn nínú ìwé-mímọ́ pé, Jésù ni Kíríṣítí.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 18