Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 18:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Lẹ́yin nǹkan wọ̀nyí, Pọ́ọ̀lù jáde kúrò ni Aténì, lọ sí Kọ́ríńtì;

2. Ó sì rí Júù kan tí a ń pè ní Àkúílà, tí a bí ni Pọ́ńtù, tí ó ti Ìtalì dé ní lọ́ọ́lọ́ọ́, pẹ̀lú Pírísíkílà aya rẹ̀; nítorí tí Kíláúdíù pàsẹ pé, kí gbogbo àwọn Júù jáde kúrò ní Róòmù. Ó sì tọ̀ wọ́n lọ láti rí wọn.

3. Nítorí tí òun náà jẹ́ onísẹ̀-ọwọ́ kan náà, ó bá wọn jókòó, ó sì nṣíṣẹ́: nítorí àgọ́ pípa ni iṣẹ́-ọwọ́ wọn.

4. Ó sì ń fọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀ fún wọn nínú ṣínágógù lọ́jọjọ́ ìsinmi, ó sì ń yí àwọn Júù àti àwọn Gíríkì lọ́kàn padà.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 18