Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 17:16-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù dúró dè wọ́n ni Aténì, ẹ̀mí rẹ̀ ru nínú rẹ̀, nígbà tí ó rí pé ìlú náà kún fún òrìṣà.

17. Nítorí náà ó ń bá àwọn Júù fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀ nínú Sínágógù, àti àwọn olùfọkànsìn, àti àwọn tí ó ń bá pàdé lọ́jà lójoojúmọ́.

18. Nínú àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n Épíkúrè àti tí àwọn Sítííkì pàdé rẹ̀. Àwọn kan si ń wí pé, “Kín ni aláhesọ yìí yóò rí wí?” Àwọn mìíràn sì wí pé, “Ó dàbí ń wàásù Jésù, àti àjíǹde fún wọn.”

19. Wọ́n sì mú un, wọ́n sì fà á lọ ṣí Áréópágù, wọ́n wí pé, “A ha lè mọ̀ kín ni ẹ̀kọ́ titun tí ìwọ ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí jẹ́?

20. Nítorí tí ìwọ mú ohun àjèjì wá si etí wa: àwa sì ń fẹ́ mọ̀ kín ni ìtumọ̀ nǹkan wọ̀nyí.”

21. Nítorí gbogbo àwọn ará Áténì, àti àwọn àlejò tí ń ṣe àtìpó níbẹ̀ kì í ṣe ohun mìíràn jù kí a máa sọ tàbí ki a máa gbọ́ ohun titun lọ.

22. Pọ́ọ̀lù si dìde dúró láàrin Áréópágù, ó ní, “Ẹ̀yin ará Áténì, mo wòye pé ní ohun gbogbo ẹ kún fún onírúurú ìsìn jù.

23. Nítorí bí mo ti ń kọjá lọ, tí mo wo àwọn ohun tí ẹ̀yin ń sìn, mo sì rí pẹpẹ kan tí a kọ àkọlé yìí ṣí, ‘FÚN ỌLỌ́RUN ÀÌMỌ̀.’ Ǹjẹ́ ẹni tí ẹyin ń sìn ni àìmọ̀ òun náà ni èmi ń ṣọ fún yin.

24. “Ọlọ́run náà tí ó dá ayé àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀, òun náà tí í ṣe Olúwa ọ̀run àti ayé, kì í gbé ilé tí a fi ọwọ́ kọ́;

25. Bẹ́ẹ̀ ni a kì í fi ọwọ́ ènìyàn sìn ín, bí ẹni pé ó ń fẹ́ nǹkan, òun ni ó fi ìyè àti èémí àti ohun gbogbo fún gbogbo ènìyàn.

26. Ó sì tí tipàṣẹ̀ ẹnìkan dá gbogbo orílẹ̀-èdè láti tẹ̀dó sí ojú àgbáyé, ó sì ti pinnu àkókò tí a yàn tẹ́lẹ̀, àti ààlà ibùgbé wọn;

27. kí wọ́n baà lè maa wá Olúwa, bóyá wọn yóò lè sàfẹrí rẹ̀, ki wọn sì rí í. Bí ó tílẹ̀ jẹ pé kò jìnnà sí olúkúlùkù wa:

28. Nítorí nínú rẹ̀ ni àwa wà láàyè, tí a ń rìn kiri, tí a sì ní ẹ̀mí wa: bí àwọn kan nínú àwọn akéwì tí ẹ̀yin tìkarayín tí wí pé, ‘Àwa pẹ̀lú sì jẹ́ ọmọ rẹ̀.’

29. “Ǹjẹ́ bí àwa bá jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, kò yẹ fún wa láti rò pé, Ẹni-Ijọ́sìn-sí wa dàbí wúrà, tàbí fàdákà, tàbí òkúta, tí a fi ọgbọ́n àti ìmọ̀ ènìyàn ya èré àwòrán rẹ̀.

30. Pẹ̀lúpẹ̀lù ìgbà àìmọ̀ yìí ni Ọlọ́run tí gbójú fò dá; ṣùgbọ́n nísìnyìí ó pàṣẹ fún gbogbo ènìyàn níbi gbogbo láti ronúpìwàdà;

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 17