Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 15:32-41 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

32. Bí Júdà àti Sílà tìkara wọn ti jẹ́ wòlíì pẹ̀lú, wọ́n fi ọ̀rọ̀ púpọ̀ gba àwọn arákùnrin níyànjú, wọ́n sì mú wọn lọ́kàn le.

33. Nígbà tí wọn sì pẹ́, díẹ̀, àwọn arákùnrin rán wọn padà lọ ni àlàáfíà sí ọ̀dọ̀ àwọn tí ó rán wọn wá.

34. (Ṣùgbọ́n o wú Sílà láti gbé ibẹ̀.)

35. Pọ́ọ̀lù àti Bánábà sì dúró díẹ̀ ni Ańtíókù, wọ́n ń kọ́ní, wọ́n sì ń wàásù ọ̀rọ̀, Olúwa, àti àwọn púpọ̀ mìíràn pẹ̀lú wọn.

36. Lẹ́yìn ọjọ́ mélóòkán. Pọ́ọ̀lù sì sọ fún Bánábà pé, “Jẹ́ kí a tún padà lọ bẹ àwọn arákùnrin wa wò, bí wọn ti ń ṣe sí ni ìlú gbogbo tí àwa ti wàásù ọ̀rọ̀ Olúwa.”

37. Bánábà sì pinnu rẹ̀ láti mú Jòhánù lọ pẹ̀lú wọn, ẹni tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Máàkù.

38. Ṣùgbọ́n Pọ́ọ̀lù rò pé, kò yẹ láti mú un lọ pẹ̀lú wọn, ẹni tí ó fi wọn sílẹ̀ ni Páḿfílíà, tí kò sì bá wọn lọ sí iṣẹ́ náà.

39. Ìjà náà sì pọ̀ tó bẹ́ẹ̀, tí wọn ya ara wọn sì méjì: Bánábà sì mu Máàkù ó tẹ ọkọ́ létí lọ sí Sáípúrọ́sì.

40. Ṣùgbọ́n Pọ́ọ̀lù yan Sílà, ó sì lọ, bí a ti fi lé oore-ọ̀fẹ́ Olúwa lọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin.

41. Ó sì la Síríà àti Kílíkíà lọ, ó ń mú ìjọ ní ọkàn le.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 15