Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 15:20-39 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Ṣùgbọ́n kí a kọ̀wé si wọn, kí wọ́n fà sẹ̀hín kúrò nínú èérí òrìṣà, àti kúrò nínú àgbèrè, àti nínú ẹ̀jẹ̀.

21. Mósè nígbà àtijọ́, sá ní àwọn ti ń wàásù rẹ̀, ni ìlú gbogbo, a máa ń kà á nínú sínágọ́gù ni ọjọ́jọ́ ìsinmi.”

22. Nígbà nàá ni ó tọ́ lójú àwọn àpósítélì, àti àwọn alàgbà pẹ̀lú gbogbo ìjọ, láti yan ènìyàn nínú wọn, àti láti rán wọ́n lọ sí Áńtíókù pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù àti Bánábà: Júdà ti a ń pè àpèlé rẹ̀ ní Básábà, àti Sílà, ẹni tí ó lórúkọ nínú àwọn arákùnrin.

23. Wọn sì kọ ìwé lé wọn lọ́wọ́ báyìí pé:Àwọn àpósítélì, àti àwọn alàgbà,Tí ó jẹ̀ ti aláìkọlà tí ó wà ní Áńtíókù, àti ní Síríà: àti ní Kílíkíà.

24. Níwọ̀n bí àwa ti gbọ́ pé, àwọn kan ti ó ti ọ̀dọ̀ wa jáde wá ń fi ọ̀rọ̀ yọ yín lẹ́nu, tí wọ́n ń yí yín lọ́kàn po, (wí pé, Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ ṣàìmá kọ ilà, àti ṣaima pa òfin Mósè mọ́:) ẹni tí àwa kò fún ní àṣẹ:

25. Ó yẹ lójú àwa, bí àwa ti fi ìmọ̀ sọ̀kan láti yan ènìyàn láti rán wọn sí yín, pẹ̀lú Bánábà àti Pọ́ọ̀lù àwọn olùfẹ́ wa.

26. Àwọn ọkùnrin ti ó fi ọkàn wọn wéwu nítorí orúkọ Olúwa wa Jésù Kírísítì.

27. Nítorí náà àwa rán Júdà àti Sílà àwọn tí yóò sì fi ọ̀rọ̀ ẹnu sọ ohun kan náà fún yín.

28. Nítorí ó dára lójú Ẹ̀mí Mímọ́, àti lójú wa, kí a má ṣe di ẹrù kà yín, bí kò ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí tí ó ṣe pàtàkì;

29. Kí ẹ̀yin fà sẹ̀yìn kúrò nínú ẹran àpabọ òrìṣà, àti nínú ẹ̀jẹ̀ àti nínú ohun ìlọ́lọ́rùn-pa, àti nínú àgbérè: nínú ohun tí, bí ẹ̀yin bá pa ara yín mọ́ kúrò, ẹ̀yin ó ṣe rere.Àlàáfíà.

30. Ǹjẹ́ nígbà tí wọ́n sì fi wọ́n sílẹ̀ láti lọ, wọ́n sọ̀kalẹ̀ wá si Áńtíókù: nígbà tí wọn sì pé àwọn ìjọ pọ̀, wọn fi ìwé náà fún wọn.

31. Nígbà tí wọn sì kà á, wọ́n yọ̀ fún ìtùnú náà.

32. Bí Júdà àti Sílà tìkara wọn ti jẹ́ wòlíì pẹ̀lú, wọ́n fi ọ̀rọ̀ púpọ̀ gba àwọn arákùnrin níyànjú, wọ́n sì mú wọn lọ́kàn le.

33. Nígbà tí wọn sì pẹ́, díẹ̀, àwọn arákùnrin rán wọn padà lọ ni àlàáfíà sí ọ̀dọ̀ àwọn tí ó rán wọn wá.

34. (Ṣùgbọ́n o wú Sílà láti gbé ibẹ̀.)

35. Pọ́ọ̀lù àti Bánábà sì dúró díẹ̀ ni Ańtíókù, wọ́n ń kọ́ní, wọ́n sì ń wàásù ọ̀rọ̀, Olúwa, àti àwọn púpọ̀ mìíràn pẹ̀lú wọn.

36. Lẹ́yìn ọjọ́ mélóòkán. Pọ́ọ̀lù sì sọ fún Bánábà pé, “Jẹ́ kí a tún padà lọ bẹ àwọn arákùnrin wa wò, bí wọn ti ń ṣe sí ni ìlú gbogbo tí àwa ti wàásù ọ̀rọ̀ Olúwa.”

37. Bánábà sì pinnu rẹ̀ láti mú Jòhánù lọ pẹ̀lú wọn, ẹni tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Máàkù.

38. Ṣùgbọ́n Pọ́ọ̀lù rò pé, kò yẹ láti mú un lọ pẹ̀lú wọn, ẹni tí ó fi wọn sílẹ̀ ni Páḿfílíà, tí kò sì bá wọn lọ sí iṣẹ́ náà.

39. Ìjà náà sì pọ̀ tó bẹ́ẹ̀, tí wọn ya ara wọn sì méjì: Bánábà sì mu Máàkù ó tẹ ọkọ́ létí lọ sí Sáípúrọ́sì.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 15