Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 13:13-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù àti àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ si ṣíkọ̀ ni Páfòsì wọ́n wá sí Págà ni Pàmífílíà: Jòhánù sì fi wọ́n sílẹ̀, ó sì padà lọ sí Jerúsálémù.

14. Nígbà ti wọ́n sì là Págà kọjá, wọ́n wá sí Pìsìdíà ní Áńtíókù. Wọ́n sì wọ inú sínágọ́gù ní ọjọ́ ìsinmi, wọ́n sì jókòó.

15. Lẹ́yìn kíka ìwé òfin àti ìwé àwọn wòlíì, àwọn olórí sínágọ́gù ránṣẹ́ sí wọn, pé, “Ará, bí ẹ̀yin bá ni ọ̀rọ̀ ìyànjú kan fún àwọn ènìyàn, ẹ sọ ọ́!”

16. Pọ́ọ̀lù sì dìde dúró, ó sì juwọ́ sí wọn, ó ní, “Ẹ̀yin Ísírẹ́lì, àti ẹ̀yin ti ó bẹ̀rù Ọlọ́run, ẹ fi etí sílẹ̀ sí mi!

17. Ọlọ́run àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì yìí yan àwọn baba wa, ó sì gbé àwọn ènìyàn náà lékè, nígbà tí wọ́n ṣe àtìpó ní ilẹ̀ Íjíbítì, apá gíga ni ó sì fi mú wọn jáde kúrò nínú rẹ̀,

18. ní ìwọ̀n ìgbà ogójì ọdún ni ó fi mú sùúrú fún ìwà wọn ní ijù,

19. nígbà tí ó sì ti run orílẹ̀-èdè méje ni ilẹ̀ Kénááni, ó sì fi ilẹ̀ wọn fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ni ìní.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 13