Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 13:12-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Nígbà tí baálẹ̀ rí ohun tí ó ṣe, ó gbàgbọ́, ẹnu sì yà á sì ẹ̀kọ́ Olúwa.

13. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù àti àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ si ṣíkọ̀ ni Páfòsì wọ́n wá sí Págà ni Pàmífílíà: Jòhánù sì fi wọ́n sílẹ̀, ó sì padà lọ sí Jerúsálémù.

14. Nígbà ti wọ́n sì là Págà kọjá, wọ́n wá sí Pìsìdíà ní Áńtíókù. Wọ́n sì wọ inú sínágọ́gù ní ọjọ́ ìsinmi, wọ́n sì jókòó.

15. Lẹ́yìn kíka ìwé òfin àti ìwé àwọn wòlíì, àwọn olórí sínágọ́gù ránṣẹ́ sí wọn, pé, “Ará, bí ẹ̀yin bá ni ọ̀rọ̀ ìyànjú kan fún àwọn ènìyàn, ẹ sọ ọ́!”

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 13