Ìṣe Àwọn Àpósítélì 12:20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)
Héródù sí ń bínú gidigidi sí àwọn ará Tírè àti Sídónì; ṣùgbọ́n wọ́n fi ìmọ̀sọ̀kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀, nígbà tí wọn sì ti tu Bílásítù ìwẹ̀fà ọba lójú, wọn ń bẹ̀ẹ̀ fún àlàáfíà, nítorí pé ìlú ọba náà ni ìlú tiwọn ti ń gba oúnjẹ.