Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 10:36-48 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

36. Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run rán sí àwọn ọmọ Isírẹ́lì, nígbà tí a wàásù àlàáfíà nípa Jésù Kírísítì (Òun ni Olúwa ohun gbogbo)

37. Ẹ̀yin náà mọ ọ̀rọ̀ náà tí a kéde rẹ̀ yíká gbogbo Jùdíà, tí a bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ láti Gálílì, lẹ́yìn bamitíìsímù ti Jòhánù wàásù rẹ̀.

38. Àní gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run Ẹ̀mi Mímọ́ àti agbára; ẹni tí ó ń kiri ṣe oore, ó ń ṣe ìmúláradá gbogbo àwọn tí Èṣù sì ń pọ́n lójú; nítorí Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀.

39. “Àwa sì ni ẹlẹ́rì gbogbo ohun tí ó ṣe, ní ilẹ̀ àwọn Júù, àti ni Jerúsálémù. Ẹni tí wọ́n pa nípa gbígbékọ́ sí orí igi.

40. Òun ni Ọlọ́run jí dìde ni ọjọ́ kẹta ó sì fi i hàn gbangba.

41. Kì í ṣe fún gbogbo ènìyàn, bí kò ṣe fún àwa ti a jẹ́ ẹlẹ́rìí ti a ti lọ́wọ́ Ọlọ́run yàn tẹ́lé, ti a bá a jẹ, ti a sì bá à mu lẹ́yìn ìgbà ti ó jindé kúrò nínú òkú.

42. Ó sì paṣẹ fún wa láti wàásù fún àwọn ènìyàn, àti láti jẹ́rìí pé, òun ni a ti ọwọ́ Ọlọ́run yàn ṣe Onídàjọ́ ààyè àti òkú.

43. Òun ni gbogbo àwọn wòlíì jẹ́rìí sì pé, ẹnikẹ́ni ti ó bá gbà á gbọ́ yóò rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà nípa orúkọ rẹ̀.”

44. Bí Pétérù sì ti ń sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí lẹ́nu, Ẹ̀mí Mímọ́ bà lé gbogbo àwọn ti ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà.

45. Ẹnu sì yà àwọn onígbàgbọ́ ti ìkọlà tí wọ́n bá Pétérù wá, nítorí ti a tu ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ sórí àwọn aláìkọlà pẹ̀lú.

46. Nítorí wọ́n gbọ́, wọ́n ń fọ onírúurú èdè, wọn sì yin Ọlọ́run lógo.Nígbà náà ni Pétérù dáhùn wí pé,

47. “Ẹnikẹ́ni ha lè ṣòfin omi, kí a má bamítíìsì àwọn wọ̀nyí tí wọ́n gba Ẹ̀mí Mímọ́ bí àwa?”

48. Ó sì pàsẹ kí a bamitíìsì wọn ni orúkọ Jésù Kírísitì. Nígbà náà ni wọ́n bẹ̀ ẹ́ kí ó dúró ni ijọ́ mélòókan.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 10