Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 10:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọkùnrin kan sì wà ni Kesaríà ti a ń pè ní Kọ̀nélíù, balógun ọ̀rún ti ẹgbẹ́ ọmọ-ogun tí a ń pè ni Ítálì.

2. Olùfọkànsìn, àti ẹni ti ó bẹ̀rù Ọlọ́run tilé tilé rẹ̀ gbogbo, ẹni tí ó ń tọrẹ àánú púpọ̀ fún àwọn ènìyàn, tí ó sì ń gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run nígbà gbogbo.

3. Níwọ̀n wákàtí kẹ́sàn-án ọjọ́, ó rí nínú ìran kedere ańgẹ́lì Ọlọ́run kan wọlé tọ̀ ọ́ wá, ó sì wí fún un pé, “Kọ̀nélíù!”

4. Nígbà tí ó sì tẹjúmọ́ ọn, ti ẹ̀rù sì bà á, ó ní, “Kí ni, Olúwa?”Ó sì wí fún un pé, “Àdúrà rẹ àti ọrẹ-àánú, tìrẹ gòkè lọ ṣíwájú Ọlọ́run fún ìrántí.

5. Sì rán ènìyàn nísinsìnyìí lọ sí Jópà, kí wọn sì pe Símónì wá, ẹni ti àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Pétérù.

6. Ó wọ̀ sí ilé Símónì aláwọ, tí ilé rẹ̀ wà létí òkun; òun ni yóò sọ fún ọ bí ìwọ ó ti ṣe.”

7. Nígbà tí ańgẹ́lì náà tí ó bá Kọ̀nélíù sọ̀rọ̀ sì fi i sílẹ̀ lọ ó pe méjì nínú àwọn ìránṣẹ́ ilé rẹ̀, ati ọmọ ogun olùfọkànsìn kan, nínú àwọn ti ó máa ń dúró tì í nígbà gbogbo.

8. Nígbà tí ó sì tí ṣàlàyé ohun gbogbo fún wọn, ó rán wọn lọ sí Jópà. A fi ran hàn Pétérù pẹ̀lú.

9. Ni ijọ́ kéjì bí wọ́n ti ń lọ lọ́nà àjò wọn, tí wọ́n sì súnmọ́ ilé náà, Pétérù gun òkè ilé lọ gbàdúrà ni ìwọ̀n wákàtí kẹfà ọjọ́:

10. Ebi sì pa á gidigidi, ó sì ń fẹ́ láti jẹun: ó bọ́ sí ojúran.

11. Ó sì rí ọ̀run ṣí, ohun-èlò kan si sọ̀kálẹ̀ bí gọ̀gọ̀wú ńlá, tí a ti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, sọ̀kalẹ̀ sí ilẹ̀:

12. Nínú rẹ̀ ni onírúurú ẹrankọ ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin wà, ati ohun tí ń rákò ni ayé àti ẹyẹ ojú ọ̀run.

13. Ohùn kan si fọ̀ sí i pe, “Dìde, Pétérù; máa pa kí o sì má a jẹ.”

14. Ṣùgbọn Pétérù dáhùn pé, “Àgbẹdọ̀, Olúwa; nítorí èmi kò jẹ ohun èèwọ̀ ati aláìmọ́ kan rí.”

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 10