Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Gálátíà 5:12-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Èmi ìbá fẹ́ kí àwọn tí ń yọ yín lẹ́nu tilẹ̀ gé ẹ̀yà-ara wọn kan kúrò.

13. Nítorí a ti pè yín sí òmìnira, ará kìkì pé kí ẹ má ṣe lo òmìnira yín bí àǹfààní sípa ti ara, ṣùgbọ́n ẹ máa fi ìfẹ́ sin ọmọnìkejjì yín.

14. Nítorí pé a kó gbogbo òfin já nínú èyí pé, “Ìwọ fẹ́ ọmọnìkejì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.”

15. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá ń bu ara yín ṣán, tí ẹ sì ń jẹ ara yín run, ẹ kíyèsára kí ẹ má ṣe pa ara yín run.

16. Ǹjẹ́ mo ní, Ẹ máa rìn nípa ti Ẹ̀mí, ẹ̀yin kì yóò sì mú ìfẹ́kúfẹ́ ti ara ṣẹ.

17. Nítorí ti ara ń ṣe ìfẹ́kúfẹ́ lòdì sí Ẹ̀mí, àti Ẹ̀mí lòdì sí ara: àwọn wọ̀nyí sì lòdì sí ara wọn; kí ẹ má baà lè ṣe ohun tí ẹ̀yin ń fẹ́.

18. Ṣùgbọ́n bí a bá ń ti ọwọ́ Ẹ̀mi samọ̀nà yín, ẹ̀yin kò sí lábẹ́ òfin.

19. Ǹjẹ́ àwọn iṣẹ́ tí ara farahàn, tíí ṣe wọ̀nyí; panṣágà, àgbèrè, ìwà èérí, wọ̀bìà,

20. Ìbọ̀rìṣà, oṣó, ìkórira, ìjà, ìlara, ìbínú, ìmọtara-ẹni nìkan, ìyapa, ẹ̀kọ́-òdí.

21. Àrankan, ìpànìyàn, ìmutípara, ìréde-òru, àti irú ìwọ̀nyí; àwọn ohun tí mo ń wí fún yín tẹ́lẹ̀, gẹ́gẹ́ bí mo ti wí fún yín tẹ́lẹ̀ rí pé, àwọn tí ń ṣe nǹkan báwọ̀nyí kì yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.

22. Ṣùgbọ́n èèso ti Ẹ̀mí ni ìfẹ́, ayọ̀, àlàáfíà, ìpamọ́ra, ìwàpẹ̀lẹ́, ìṣoore, ìgbàgbọ́,

23. Ìwà-tútù, àti ìkóra-ẹni níjanu: òfin kan kò lòdì sí irú wọ̀nyí,

Ka pipe ipin Gálátíà 5