Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Gálátíà 3:3-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Báyìí ni ẹ̀yin ṣe gọ̀ tó bí? Lẹyin tí ẹ bẹ̀rẹ̀ nípa tí Ẹ̀mí, a há ṣe yín pé nísinsìnyìí nípa tí ara?

4. Ẹ̀yin ha ti jìyà ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan wọ̀nyí lásán? Bí ó bá ṣe pé nítoótọ́ lásán ni.

5. Ṣé Ọlọ́run fún yín ní Ẹ̀mí rẹ̀, tí ó sì ṣe iṣẹ́-ìyanu láàrin yín nítorí tí ẹ̀yin pa òfin mọ, tàbí nítorí ẹ ní ìgbàgbọ sí ohun tí ẹ gbọ́?

6. Gẹ́gẹ́ bí Ábúráhámù “Ó gba Ọlọ́run gbọ́, a sì kà á sí fún un ní òdodo.”

7. Ẹ jẹ́ kí ó yé é yín nígbà náà pé, àwọn ti ó gbàgbọ́, àwọn náà ní í ṣe ọmọ Ábúráhámù.

8. Bí ìwé-mímọ́ sì tí wí tẹ́lẹ̀ pé, Ọlọ́run yóò dá aláìkọlà láre nípa ìgbàgbọ́, ó tí wàásù ìyìn rere ṣáájú fún Ábúráhámù, ó ń wí pé, “Nínú rẹ̀ ni a ó bùkún fún gbogbo orílẹ̀-èdè.”

9. Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí i ṣe tí ìgbàgbọ́ jẹ́ ẹni alábùkúnfún pẹ̀lú Ábúráhámù olódodo.

10. Nítorí pé iye àwọn tí ń bẹ ni ipa iṣẹ́ òfin ń bẹ lábẹ́ ègún: nítorí tí a tí kọ ọ́ pé, “Ìfibú ni olúkúlùkù ẹni tí kò dúró nínú ohun gbogbo tí a kọ sínú ìwé òfin láti máa ṣe wọ́n.

11. Nítorí ó dánilójú pé, a kò dá ẹnìkẹ́ni láre níwájú Ọlọ́run nípa iṣẹ́ òfin: nítorí pé, olódodo yóò yè nípa ìgbàgbọ́.”

12. Òfin kì í sì í ṣe ti ìgbàgbọ́: ṣùgbọ́n “Ẹnikẹ́ni tí ń se wọn yóò yè nípaṣẹ̀ wọn.”

13. Kírísítì ti rà wá padà kúrò lọ́wọ́ ègún òfin, ẹni tí a fi ṣe ègún fún wa: nítorí tí a ti kọ ọ́ pé, “Ìfibú ni olúkúlùkù ẹni tí a fi kọ́ sórí igi.”

14. Kí ìbùkún Ábúráhámù ba à lè wá sórí àwọn aláìkọlà nípa Kírísítì Jésù; kí àwa ba à lè gba ìlérí Ẹ̀mí nípa ìgbàgbọ́.

15. Ará, èmi ń ṣọ̀rọ̀ bí ènìyàn: bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé májẹ̀mú ènìyàn ni, ṣùgbọ́n bí a ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀, kò sí ẹni tí ó lè sọ ọ́ di asán, tàbí tí ó lè fi kún un mọ́.

16. Ǹjẹ́ fún Ábúráhámù àti fún irú ọmọ rẹ̀ ni a ti ṣe àwọn ìlérí náà. Òun kò ṣe wí pé, “Àti fún irú-ọmọ rẹ̀,” èyí tí í ṣe Kírísítì.

17. Èyí tí mò ń wí ni pé: Májẹ̀mu tí Ọlọ́run ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ níṣáájú, òfin ti ó dé lẹ́yìn ọgbọ̀n-lé-nírinwó ọdún kò lè sọ ọ́ di asán, tí à bá fi mú ìlérí náà di aláìlágbára.

18. Nítorí bí ìjogún náà bá ṣe ti òfin kì í ṣe ti ìlérí mọ́: ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti fi í fún Ábúráhámù nípa ìlérí.

19. Ǹjẹ́ kí há ni òfin? A fi kún un nítorí ìrékọjá títí irú-ọmọ tí a ti ṣe ìlérí fún yóò fi dé; a sì tipaṣẹ̀ àwọn áńgẹ́lì lànà rẹ̀ láti ọwọ́ alárinà kan wá.

20. Ǹjẹ́ alárinà láàrin ẹgbẹ́ tí ó ju ọ̀kan ṣoṣo lọ; ṣùgbọ́n ọ̀kan ni Ọlọ́run.

21. Nítorí náà òfín ha lòdì sí àwọn ìlérí Ọlọ́run bí? Kí a má rí i; Nítorí ìbá ṣe pé a ti fi òfin kan fún ni tí ó lágbára láti sọni di ààyè nítòótọ́ òdodo ìbá ti tipasẹ̀ òfin wà.

Ka pipe ipin Gálátíà 3