Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Gálátíà 1:15-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó wú Ọlọ́run ẹni tí ó yà mí sọ́tọ̀ láti inú ìyá mi wá, tí ó sì pé mi nípa oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀.

16. Láti fi ọmọ rẹ̀ hàn nínú mi, kì èmi lè máa wàásù rẹ̀ láàrin àwọn aláìkọlà; èmi kò wá ìmọ̀ lọ sọ́dọ̀ ẹnikẹ́ni,

17. bẹ́ẹ̀ ni èmi kò gòkè lọ sì Jerúsálémù tọ àwọn tí í ṣe Àpósítélì ṣáájú mi: ṣùgbọ́n mo lọ sí Árábíà, mo sì tún padà wá sí Dámásíkù.

18. Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta, nígbà náà ni mo gòkè lọ sì Jerúsálémù láti lọ kì Pétérù, mo sì gbé ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní ìjọ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún,

19. Èmi kò ri ẹlòmíràn nínú àwọn tí ó jẹ́ Àpósítélì, bí kò ṣe Jákọ́bù arákùnrin Olúwa.

20. Nǹkan tí èmi ń kọ̀wé sí yín yìí kíyèsí i, níwájú Ọlọ́run èmi kò ṣèké.

21. Lẹ́yìn náà mo sì wá sí agbègbè Síríà àti ti Kílíkáíà;

22. Mo sì jẹ́ ẹni tí a kò mọ̀ lójú fún àwọn ìjọ tí ó wà nínú Kírísítì ni Jùdíà:

23. Wọ́n kàn gbọ́ ìròyìn wí pé, “Ẹni tí ó tí ń ṣe inúnibíni sí wa rí, ní ìsinsìn yìí ti ń wàásù ìgbàgbọ́ náà tí ó ti gbìyànjú láti bàjẹ́ nígbà kan rí.”

24. Wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo nítorí mi.

Ka pipe ipin Gálátíà 1