Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Fílímónì 1:21-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Ìgbẹ́kẹ̀lé ti mo ní pé ìwọ yóò gbọ́ràn, ni mo fi kọ ìwé yìí ránsẹ́ sí ọ. Mo mọ̀ dájú pé ìwọ yóò se ju bí mo ti béèrè lọ.

22. Ó ku ohun kan: Ṣe ìtọ́jú ìyara àlejò rẹ sílẹ̀ fún mi, nítorí mo ní ìgbàgbọ́ pé a óò tú mi sílẹ̀ fún yín ní ìdáhùn sí àdúrà yín.

23. Ẹ́páfírà, òǹdè ẹlẹgbẹ́ mi nínú Kírísítì Jésù kí ọ.

24. Máàkù kí ọ pẹ̀lú Ańsíbákù, Dẹ́mà àti Lúùkù, àwọn alábàáṣiṣẹ́ mi.

25. Kí Oore-ọ̀fẹ́ Jésù Kírísítì Olúwa wa wà pẹ̀lú ẹ̀mí yín.

Ka pipe ipin Fílímónì 1