orí

  1. 1

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Fílímónì 1 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Ìkíni

1. Èmi Pọ́ọ̀lù, ẹni tí a fi sẹ́wọ̀n nítorí pé ó ń wàásù ìyìn rere Jésù Kírísítì àti Tímótíù arákùnrin wa.Sí Fílímónì ọ̀rẹ́ wa ọ̀wọ́n àti alábàáṣiṣẹ́ wa,

2. sí Áfíà arábìnrin wa, sí Ákípọ́sì ẹni tó jẹ́ jagunjagun fún àgbélébùú náà àti sí ìjọ àwọn Kírísítẹ́nì tí ó ń pàdé nínú ilé rẹ:

3. Oore-Ọ̀fẹ́ fún un yín àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa àti Jésù Kírísítì.

Àwọn Ọpẹ́ àti Àdúrà

4. Èmi máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà tí mo bá rántí rẹ nínú àdúrà mi,

5. nítorí mo ń gbọ́ nípa ìgbàgbọ́ rẹ nínú Jésù Olúwa àti nípa ìfẹ́ rẹ sí àwọn ènìyàn mímọ́.

6. Èmi ń gbàdúrà pé, bí ìwọ ti ń ṣe alábàápín nínú ìgbàgbọ́ rẹ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, pé kí ìgbàgbọ̀ náà lè mú ọkàn wọn dúró gbọ-ingbọ-in, gẹ́gẹ́ bí wọn ti rí àwọn ọ̀rọ̀ ohun rere tí ó ń bẹ nínú ayé rẹ, èyí tí ó ti ọ̀dọ̀ Kírísítì wá.

7. Ìfẹ́ rẹ ti fún mi ní ayọ̀ púpọ̀ àti ìgboyà, nítorí ìwọ, arákùnrin ti tu ọkàn àwọn ènìyàn mímọ́ lara.

Pọ́ọ̀lù Bẹ̀bẹ̀ Fún Onísímù

8. Nítorí náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ninú Kírísítì mo ní ìgboyà púpọ̀ láti pàṣẹ ohun ti ó yẹ kí ó ṣe fún ọ,

9. ṣíbẹ̀ nítorí ìfẹ́ èmí kúkú bẹ̀ ọ́. Èmi gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù, arúgbó, àti nísinsìnyìí òǹdè Jésù Kírísítì.

10. Èmí bẹ̀ ọ́ nítorí ọmọ mi Ónísímu, ẹni tí ó di ọmọ nígbà tí mo wà nínú ìdè.

11. Nígbà kan rí, kò wúlò fún ọ, ṣùgbọ́n ní báyìí, ó ti wúlò fún ọ àti fún èmi pàápàá.

12. Èmi rán an nísinsìn yìí, àní ẹni ọkàn mi padà sí ọ̀dọ̀ rẹ.

13. Èmi ìbá fẹ́ láti dá a dúró sọ́dọ̀ mi níhìn-ín, kí ó baà dípò rẹ láti máa ràn mí lọ́wọ́ nígbà tí mo wà nínú ìdè nítorí ìyìn rere

14. ṣùgbọ́n èmi kò fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ rárá láìgba ìyọ̀ǹda ní ọwọ́ rẹ, kí oore tí ìwọ bá ṣe má baà jẹ́ ìfipámúniṣe bí kò ṣe ìfìfẹ́ṣe.

15. Bóyá ìdí rẹ̀ tí òun fi yẹra kúrò lọ́dọ̀ rẹ fún ìgbà díẹ̀ ni pé kí ìwọ kí ó lè gbà á padà sọ́dọ̀ títí láé;

16. Kì í wá ṣe bí ẹrú mọ́, ṣùgbọ́n bí ẹni ti ó sàn ju ẹrú lọ, gẹ́gẹ́ bí arákùnrin. Ó ṣọ̀wọ́n fún mi jọjọ, ṣùgbọ́n ó ṣọ̀wọ́n fún ọ jù nípa ti ara àti gẹ́gẹ́ bí arákùnrin nínú Olúwa.

17. Nítorí náà bí ìwọ bá kà mí sí ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tẹ́wọ́ gbà á bí ìwọ yóò ti tẹ́wọ́ gbà mí.

18. Bí ó bá ti ṣe ọ́ ní ibi kan tàbí jẹ ọ́ ní gbésè ohun kan, kà á sí mi lọ́rùn.

19. Èmi Pọ́ọ̀lù, ni mo fi ọwọ́ ara mi kọ ìwé yìí; èmi yóò san án padà láì tilẹ̀ níí sọ nípa pé ìwọ pàápàá jẹ mi ní gbésè ara rẹ.

20. Èmi ń fẹ́, arákùnrin, pé kí èmi kí ó lè ni àǹfààní kan láti ọ̀dọ̀ rẹ nínú Olúwa; fi ayọ̀ rẹ kún ọkàn mi nínú Jésù.

21. Ìgbẹ́kẹ̀lé ti mo ní pé ìwọ yóò gbọ́ràn, ni mo fi kọ ìwé yìí ránsẹ́ sí ọ. Mo mọ̀ dájú pé ìwọ yóò se ju bí mo ti béèrè lọ.

22. Ó ku ohun kan: Ṣe ìtọ́jú ìyara àlejò rẹ sílẹ̀ fún mi, nítorí mo ní ìgbàgbọ́ pé a óò tú mi sílẹ̀ fún yín ní ìdáhùn sí àdúrà yín.

23. Ẹ́páfírà, òǹdè ẹlẹgbẹ́ mi nínú Kírísítì Jésù kí ọ.

24. Máàkù kí ọ pẹ̀lú Ańsíbákù, Dẹ́mà àti Lúùkù, àwọn alábàáṣiṣẹ́ mi.

25. Kí Oore-ọ̀fẹ́ Jésù Kírísítì Olúwa wa wà pẹ̀lú ẹ̀mí yín.