Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Fílímónì 1:11-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Nígbà kan rí, kò wúlò fún ọ, ṣùgbọ́n ní báyìí, ó ti wúlò fún ọ àti fún èmi pàápàá.

12. Èmi rán an nísinsìn yìí, àní ẹni ọkàn mi padà sí ọ̀dọ̀ rẹ.

13. Èmi ìbá fẹ́ láti dá a dúró sọ́dọ̀ mi níhìn-ín, kí ó baà dípò rẹ láti máa ràn mí lọ́wọ́ nígbà tí mo wà nínú ìdè nítorí ìyìn rere

14. ṣùgbọ́n èmi kò fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ rárá láìgba ìyọ̀ǹda ní ọwọ́ rẹ, kí oore tí ìwọ bá ṣe má baà jẹ́ ìfipámúniṣe bí kò ṣe ìfìfẹ́ṣe.

15. Bóyá ìdí rẹ̀ tí òun fi yẹra kúrò lọ́dọ̀ rẹ fún ìgbà díẹ̀ ni pé kí ìwọ kí ó lè gbà á padà sọ́dọ̀ títí láé;

16. Kì í wá ṣe bí ẹrú mọ́, ṣùgbọ́n bí ẹni ti ó sàn ju ẹrú lọ, gẹ́gẹ́ bí arákùnrin. Ó ṣọ̀wọ́n fún mi jọjọ, ṣùgbọ́n ó ṣọ̀wọ́n fún ọ jù nípa ti ara àti gẹ́gẹ́ bí arákùnrin nínú Olúwa.

17. Nítorí náà bí ìwọ bá kà mí sí ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tẹ́wọ́ gbà á bí ìwọ yóò ti tẹ́wọ́ gbà mí.

18. Bí ó bá ti ṣe ọ́ ní ibi kan tàbí jẹ ọ́ ní gbésè ohun kan, kà á sí mi lọ́rùn.

19. Èmi Pọ́ọ̀lù, ni mo fi ọwọ́ ara mi kọ ìwé yìí; èmi yóò san án padà láì tilẹ̀ níí sọ nípa pé ìwọ pàápàá jẹ mi ní gbésè ara rẹ.

20. Èmi ń fẹ́, arákùnrin, pé kí èmi kí ó lè ni àǹfààní kan láti ọ̀dọ̀ rẹ nínú Olúwa; fi ayọ̀ rẹ kún ọkàn mi nínú Jésù.

21. Ìgbẹ́kẹ̀lé ti mo ní pé ìwọ yóò gbọ́ràn, ni mo fi kọ ìwé yìí ránsẹ́ sí ọ. Mo mọ̀ dájú pé ìwọ yóò se ju bí mo ti béèrè lọ.

22. Ó ku ohun kan: Ṣe ìtọ́jú ìyara àlejò rẹ sílẹ̀ fún mi, nítorí mo ní ìgbàgbọ́ pé a óò tú mi sílẹ̀ fún yín ní ìdáhùn sí àdúrà yín.

23. Ẹ́páfírà, òǹdè ẹlẹgbẹ́ mi nínú Kírísítì Jésù kí ọ.

24. Máàkù kí ọ pẹ̀lú Ańsíbákù, Dẹ́mà àti Lúùkù, àwọn alábàáṣiṣẹ́ mi.

25. Kí Oore-ọ̀fẹ́ Jésù Kírísítì Olúwa wa wà pẹ̀lú ẹ̀mí yín.

Ka pipe ipin Fílímónì 1