Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Éfésù 4:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nítorí náà, èmi òǹdè nínú Olúwa ń bẹ̀ yín pé kí ẹ̀yin máa gbé ìgbé ayé tí ó yẹ sí ìpè tí a pè yín sí.

2. Pẹ̀lu ìrẹ̀lẹ̀ gbogbo àti inú tútù, pẹ̀lú ìpamọ́ra, ẹ máa fi ìfẹ́ faradà fún ẹnìkejì yín.

3. Kí ẹ sì máa làkàkà láti pa ìṣọ̀kan Ẹ̀mí mọ́ ni ìdàpọ̀ àlàáfíà.

4. Ara kan ni ń bẹ, ati Ẹ̀mí kan, àní bí a ti pè yín sínú ìrètí kan nígbà tí a pè yín.

5. Olúwa kan, ìgbàgbọ́ kan, ìtẹ̀bọmi kan.

6. Ọlọ́run kan ati Baba gbogbo aráyé, ẹni tí ó se olórí ohun gbogbo àti nípá gbogbo àti nínú gbogbo.

7. Ṣùgbọ́n olúkúlùkù wa ni a fi oore ọ̀fẹ́ fun gẹ́gẹ́ bi òṣùwọ̀n ẹ̀bùn Kírísítì.

8. Nitorí náà a wí pé:“Nígbà tí ó gókè lọ sí ibi gíga,ó di ìgbékùn ni ìgbékùn,ó sì fi ẹ̀bùn fun ènìyàn.”

9. (Ǹjẹ́ ní ti pé, “Ó gòkè lọ” Kín ni ó jẹ́, bí kò ṣe pé ó kọ́ sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú lọ sí ìhà ìṣàlẹ̀ ilẹ̀?

10. Ẹni tí ó ti sọ̀kalẹ̀, Òun kan náà ni ó sì ti gòkè rékọjá gbogbo àwọn ọ̀run, kí ó lè kún ohun gbogbo.)

11. Ó sì ti fi àwọn kan fún ni bí àpósítélì; àti àwọn mìíràn bí i wòlíì; àti àwọn mìíràn bí ajínyìnrere, àti àwọn mìíràn bí Olùṣọ́ àgàntàn àti olùkọ́ni.

12. Fún àṣepé àwọn ènìyàn mímọ fun iṣẹ́ ìráńṣẹ́, fún ìmúdàgbà ara Kírísítì.

13. Títí gbogbo wa yóò fi dé ìṣọ̀kan ìgbàgbọ́ àti ìmọ̀ Ọmọ Ọlọ́run, títí a ó fi di ọkùnrin, títí a ó fi dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìwọ̀n Kírísítì.

Ka pipe ipin Éfésù 4