Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Éfésù 1:9-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Ó ti sọ ohun ìjìnlẹ̀ ìfẹ́ rẹ̀ di mímọ̀ fún wa, gẹ́gẹ́ bí idùnnù rere rẹ̀, èyí ti o pinnu nínú Kírísítì,

10. èyí tí yóò jẹ jáde ní kíkún àkókò, láti ṣe àkójọpọ̀ àwọn ohun tí ọ̀run àti ti ayé lábẹ́ orí kan àní Kírísítì.

11. Nínú rẹ̀ ni a yàn wá fẹ́ lẹ́hìn tí ó ti yàn wá tẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìpinu ẹni tí ń ṣiṣẹ́ ohun gbogbo ní ìbámu ìfẹ́ rẹ̀,

12. kí àwa tí ó jẹ́ àkóso ìrètí nínú Kírísítì lè jásí ìyìn ògo rẹ̀.

13. Àti ẹ̀yin pẹ̀lú darapọ̀ nínú Kírísítì nígbà tí ẹ̀yin gbọ́ ọ̀rọ̀ òtítọ́ náà àní ìyìnrere ìgbàlà yin. Lẹ́yìn tí ẹ̀yin gbàgbọ́, a lù yín ní òǹtẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ èyí tí a ti ṣe ìlérí rẹ̀ tẹ́lẹ̀,

14. èyí tí ó jẹ́ ìdánilójú àsansílẹ̀ ogún wa títí yóò fi di àkókò ìràpadà àwọn tí í ṣe ìní Ọlọ́run sí ìyìn ògo rẹ̀.

15. Nítorí ìdí èyí, nígbà tí mo ti gbúro ìgbàgbọ́ ti ń bẹ láàárin yín nínú Jésù Olúwa, àti ìfẹ́ yín sí gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́.

16. Èmi kò sì sinmi láti máa dúpẹ́ nítorí yín, àti láti máa rántí yín nínú àdúrà mi;

17. Mo sì ń bèèrè nígbàgbogbo pé kí Ọlọ́run Jésù Kírísítì Olúwa wa, Baba ògo, lè fún yín ni Ẹ̀mí nípa ti ọ̀gbọ́n àti ti ìfihàn kí ẹ̀yin kí ó tún lè mọ̀ọ́ sí i.

18. Mo tún ń gbàdúrà bákan náà wí pé kí ojú ọkan yín lè mọ́lẹ̀; kí ẹ̀yin lè mọ ohun tí ìreti ìpè rẹ̀ jẹ́, àti ọrọ̀ ògo rẹ̀ èyí tí í ṣe ogún àwọn ènìyàn mímọ́.

Ka pipe ipin Éfésù 1