Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Éfésù 1:2-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Oore ọ̀fẹ́ sí yín àti àlàáfíà, láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wá àti Jésù Kírísítì Olúwa.

3. Ògo ni fún Ọlọ́run àti Baba Jésù Kírísítì Olúwa wa, ẹni tí ó ti bùkún wa láti inú ọ̀run wá pẹ̀lú àwọn ìbùkún ẹ̀mí gbogbo nínú Kírísítì.

4. Àní, gẹ́gẹ́ bí o ti yàn wá nínú rẹ̀ ṣáájú ìpìlẹ̀ṣẹ̀ ayé, láti jẹ́ mímọ́ àti aláìlábùkù níwájú rẹ̀. Nínú ìfẹ́

5. ni Ó ti yàn wá tẹ́lẹ̀ sí ìsọdọmọ nípa Jésù Kírísítì fún ara rẹ̀, ní ìbámu ìdùnnú ìfẹ́ rẹ̀

6. fún ìyìn ogo oore ọ̀fẹ́ rẹ̀, èyí tí Ó ti fi fún wa nínú Àyànfẹ́ rẹ̀:

7. Nínú rẹ̀ ni àwa ni ìràpadà wa nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, ní ìbámu pẹ̀lú ọrọ̀ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run

8. èyí tí ó ya lù wá pẹ̀lú gbogbo ọgbọ́n àti ìmòye,

9. Ó ti sọ ohun ìjìnlẹ̀ ìfẹ́ rẹ̀ di mímọ̀ fún wa, gẹ́gẹ́ bí idùnnù rere rẹ̀, èyí ti o pinnu nínú Kírísítì,

Ka pipe ipin Éfésù 1