1. Pọ́ọ̀lù, Àpósítélì Jésù Kírísítì nípa ìfẹ́ Ọlọ́run,Sí àwọn ènìyàn mímọ́ tí ó wà ní Éfésù, àti sí àwọn olótìtọ́ nínú Kírísíti Jésù:
2. Oore ọ̀fẹ́ sí yín àti àlàáfíà, láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wá àti Jésù Kírísítì Olúwa.
3. Ògo ni fún Ọlọ́run àti Baba Jésù Kírísítì Olúwa wa, ẹni tí ó ti bùkún wa láti inú ọ̀run wá pẹ̀lú àwọn ìbùkún ẹ̀mí gbogbo nínú Kírísítì.
4. Àní, gẹ́gẹ́ bí o ti yàn wá nínú rẹ̀ ṣáájú ìpìlẹ̀ṣẹ̀ ayé, láti jẹ́ mímọ́ àti aláìlábùkù níwájú rẹ̀. Nínú ìfẹ́
5. ni Ó ti yàn wá tẹ́lẹ̀ sí ìsọdọmọ nípa Jésù Kírísítì fún ara rẹ̀, ní ìbámu ìdùnnú ìfẹ́ rẹ̀
6. fún ìyìn ogo oore ọ̀fẹ́ rẹ̀, èyí tí Ó ti fi fún wa nínú Àyànfẹ́ rẹ̀:
7. Nínú rẹ̀ ni àwa ni ìràpadà wa nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, ní ìbámu pẹ̀lú ọrọ̀ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run
8. èyí tí ó ya lù wá pẹ̀lú gbogbo ọgbọ́n àti ìmòye,
9. Ó ti sọ ohun ìjìnlẹ̀ ìfẹ́ rẹ̀ di mímọ̀ fún wa, gẹ́gẹ́ bí idùnnù rere rẹ̀, èyí ti o pinnu nínú Kírísítì,
10. èyí tí yóò jẹ jáde ní kíkún àkókò, láti ṣe àkójọpọ̀ àwọn ohun tí ọ̀run àti ti ayé lábẹ́ orí kan àní Kírísítì.