Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Hébérù 6:7-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Nítorí ilẹ̀ tí ó ń fa omi òjò tí ń rọ̀ sórí rẹ̀ nígbà gbogbo mu, tí ó sì ń hú ewébẹ̀ tí ó dára fún àwọn tí à ń tìtorí wọn ro ó pẹ̀lú, ń gba ìbùkún lọ́wọ́ Ọlọ́run.

8. Ṣùgbọ́n bí ó ba ń hu ẹ̀gún àti òṣùṣú yóò di kíkọ̀sílẹ̀, kò si jìnnà sí fífi gégùn ún, òpin èyí tí yóò wà fún ìjóná

9. Ṣùgbọ́n olùfẹ́, àwá ní ìgbàgbọ́ ohun tí ó dára jù bẹ́ẹ̀ lọ, ní ti yín, àti ohun tí ó faramọ́ ìgbàlà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé à ń ṣe báyìí sọ̀rọ̀.

10. Nítorí Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yin àti ìfẹ́ tí ẹ̀yín fihàn sí orúkọ rẹ̀, nípa iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ẹ ti ṣe fún àwọn ènìyàn mímọ́, tí ẹ sì tún ń ṣe.

11. Àwá sì fẹ́ kí olúkúlùkù yín máa fi irú àìsinmi kan náà hàn, fún ẹ̀kún ìdánilójú ìrètí títí dé òpin:

12. Kí ẹ má ṣe di onílọ̀ra, ṣùgbọ́n aláfarawé àwọn tí wọn ti ipa ìgbàgbọ́ àti sùúrù jogún àwọn ìlérí.

13. Nítorí nígbà tí Ọlọ́run ṣe ìlérí fún Ábúráhámù, bí kò ti rí ẹni tí ó pọ̀jù òun láti fi búra, ó fi ara rẹ̀ búra, wí pé,

14. “Nítòótọ́ ní bíbùkún èmi ó bùkún fún ọ, àti ní bíbísí èmi ó sì mú ọ bí sí i.”

15. Bẹ́ẹ̀ náà sì ni, lẹ̀yìn ìgbà tí Ábúráhámù fi súúrù dúró, ó ri ìlérí náà gbà.

16. Nítorí ènìyàn a máa fi ẹni tí ó pọ̀jù wọ́n lọ búra: ìbúra náà a sì fi òpin sí gbogbo ìjiyàn wọn fún ìfẹ̀ṣẹ̀ múlẹ̀ ọ̀rọ̀.

Ka pipe ipin Àwọn Hébérù 6