Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Hébérù 5:3-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Nítorí ìdí èyí ni ó ṣe yẹ, bí ó ti ń rú ẹbọ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn ènìyàn rẹ̀, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ní ń se fún ara rẹ̀ náà.

4. Ko sí ẹni tí o gba ọlá yìí fún ara rẹ̀, bí kò se ẹni tí a pè láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá gẹ́gẹ́ bí a ti pe Árọ́nì.

5. Bẹ́ẹ̀ ni Kírísítì pẹ̀lú kò si ṣe ara rẹ̀ lógo láti jẹ́ olórí àlùfáà; bí kò ṣe ẹni tí o wí fún ún pé,“Ìwọ ni ọmọ mi,lónìn-ín ni mo bi ọ.”

6. Bí ó ti wí pẹ̀lú ní ibò mìíràn pé,“Ìwọ ni àlùfáà títí láéní ipasẹ̀ Melikisédékì.”

7. Ní ìgbà ọjọ́ Jésù nínú ayé, ó fi ẹkún rara àti omije gbàdúrà, tí ó sì bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ ẹni tí ó lè gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú, a sì gbóhùn rẹ̀ nítorí ó ní ẹ̀mí ìbẹ̀rù Ọlọ́run rẹ̀.

8. Bí òun tilẹ̀ ń ṣe Ọmọ Ọlọ́run, síbẹ̀ ó kọ́ gbọ́ràn nípa ohun tí ó jìyà rẹ̀;

9. Bí a sì ti sọ ọ di pípé, o wa di orísun ìgbàlà àìnípẹ̀kun fún gbogbo àwọn tí ó ń gbọ tirẹ̀:

10. Tí a yàn ní Olórí àlùfáà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá ní ipasẹ̀ Melikisédékì.

11. Nípa èyí àwá ní ohun púpọ̀ láti sọ, tí ó sì ṣòro láti túmọ̀, nítorí pé ẹ yigbì ní gbígbọ́.

12. Nítorí pé báyìí ó ti yẹ kí ẹ jẹ́ olùkọ́ní, ẹ tún wà ní ẹni tí ẹnìkan yóò máa kọ́ ni ìbẹ̀rẹ̀ ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ àwọn ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ẹ sì tún di irú àwọn tí ó mu wàrà, tí wọn kò sì fẹ́ oúnjẹ líle.

13. Nítorí olúkúlùkù ẹni tí ń mu wàrà jẹ́ aláìlóye ọ̀rọ̀ òdodo: nítorí ọmọ ọwọ́ ni.

14. Ṣùgbọ́n oúnjẹ líle wà fún àwọn tí ó dàgbà, àwọn ẹni nípa ìrírí, tí wọn ń lo ọgbọ́n wọn láti fi ìyàtọ̀ sáàrin rere àti búburú.

Ka pipe ipin Àwọn Hébérù 5