Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Hébérù 3:4-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Láti ọwọ́ ènìyàn kan ni a sá à ti kọ́ olúkúlùkù ilé; ṣùgbọ́n ẹni tí ó kọ́ ohun gbogbo ni Ọlọ́run.

5. Mósè nítòótọ́ sì ṣe olóòótọ́ nínú gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ nínú ilé Ọlọ́run, bí ìránṣẹ́, fún ẹ̀rí ohun tí a ó sọ̀rọ̀ wọ̀n ní ìgbà ìkẹyìn.

6. Ṣùgbọ́n Kírísítì jẹ́ olóòtọ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọ lórí ilé Ọlọ́run; ilé ẹni tí àwá jẹ́, bí àwá bá gbẹ́kẹ̀ lé e, tí a sì di ìṣògo ìrètí wa mu ṣinṣin títí dé òpin.

7. Nítorí náà gẹ́gẹ́ bi Ẹ̀mi Mímọ́ tí wí:“Lònì-ín bí ẹ̀yín bá gbọ́ ohùn rẹ̀,

8. Ẹ má ṣe sé ọ̀kan yin le,bí ìgbà ìṣọ̀tẹ̀,bí i ní ọjọ́ ìdánwò ní ihà:

9. Níbi tí àwọn baba yín ti dán mi wò,tí wọ́n sì rí iṣẹ́ mi ní ogójì ọdún.

Ka pipe ipin Àwọn Hébérù 3