Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Hébérù 3:13-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Ṣùgbọ́n ẹ máa gba ara yín ní ìyànjù ní ojoojúmọ́, níwọ̀n ìgbà tí a bá ń pè ní “Òní,” kí a má ba à sé ọkàn ẹnìkẹni nínú yín le nípa ẹ̀tàn ẹ̀ṣẹ̀.

14. Nítorí àwá di alábàápín pẹ̀lú Kírísítì, bí àwá bá di ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìgbẹ́kẹ̀lé wa mú ṣinṣin títí dé òpin;

15. Nígbà tí a ń wí pé:“Lònì-ín bí ẹ̀yín bá gbọ́ ohùn rẹ̀,ẹ má se ọ̀kan yin le,bí ìgbà ìmúnibínú.”

16. Àwọn ta ni ó gbọ́ tí ó sì tún ṣọ̀tẹ̀? Kì í ha ṣe gbogbo àwọn tí o jáde kúrò ní Éjíbítì ní abẹ́ àkóso Mósè?

17. Àwọn ta ni ó sì bínú sí fún ogójì ọdún? Kì í ha ṣe sí àwọn tí ó dẹ́ṣẹ̀, òkú àwọn tí ó sùn ní ihà?

18. Àwọn wo ni ó búra fún pé wọn kì yóò wọ inú ìsinmi òun, bí kò ṣe fún àwọn tí ó ṣe àìgbọ́ràn?

19. Àwá sì rí i pé wọn kò lè wọ inú rẹ̀ nítorí àìgbàgbọ́.

Ka pipe ipin Àwọn Hébérù 3