Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Hébérù 3:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nítorí náà ẹ̀yin ará mímọ́, alábàápín ìpè ọ̀run, ẹ gba ti Àpósítélì àti Olórí Àlùfáà ìjẹ́wọ́ wa rò, àní Jésù;

2. Ẹni tí o ṣe olóòótọ́ si ẹni tí ó yàn án, bí Mósè pẹ̀lú tí ṣe olóòótọ́ nínú iṣẹ́ rẹ̀ gbogbo ilé Ọlọ́run.

3. Nítorí a ka ọkùnrin yìí ni yíyẹ sí ògo ju Mósè lọ níwọ̀n bí ẹni tí ó kọ́ ilé ti lọ́lá ju ilé lọ.

4. Láti ọwọ́ ènìyàn kan ni a sá à ti kọ́ olúkúlùkù ilé; ṣùgbọ́n ẹni tí ó kọ́ ohun gbogbo ni Ọlọ́run.

5. Mósè nítòótọ́ sì ṣe olóòótọ́ nínú gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ nínú ilé Ọlọ́run, bí ìránṣẹ́, fún ẹ̀rí ohun tí a ó sọ̀rọ̀ wọ̀n ní ìgbà ìkẹyìn.

6. Ṣùgbọ́n Kírísítì jẹ́ olóòtọ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọ lórí ilé Ọlọ́run; ilé ẹni tí àwá jẹ́, bí àwá bá gbẹ́kẹ̀ lé e, tí a sì di ìṣògo ìrètí wa mu ṣinṣin títí dé òpin.

7. Nítorí náà gẹ́gẹ́ bi Ẹ̀mi Mímọ́ tí wí:“Lònì-ín bí ẹ̀yín bá gbọ́ ohùn rẹ̀,

8. Ẹ má ṣe sé ọ̀kan yin le,bí ìgbà ìṣọ̀tẹ̀,bí i ní ọjọ́ ìdánwò ní ihà:

9. Níbi tí àwọn baba yín ti dán mi wò,tí wọ́n sì rí iṣẹ́ mi ní ogójì ọdún.

10. Nítorí náà a mú inú bí mi si ìran náà,mo sì wí pé, ‘Nígbà gbogbo ni wọn sìnà ní ọkàn wọn;wọn kò sì mọ ọ̀nà mi.’

Ka pipe ipin Àwọn Hébérù 3