Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Hébérù 12:2-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Kí a máa wo Jésù Olùpilẹ̀ṣẹ̀ àti aláṣepé ìgbàgbọ́ wa; ẹni nítorí ayọ̀ tí a gbé ka iwájú rẹ, tí o faradà àgbélébùú láìka ìtìjú sí, tí ó sì jóko lọ́wọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọ́run.

3. Má a ro ti ẹni tí ó faradà irú sọ̀rọ̀-òdì yìí láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlẹ́sẹ̀ si ara rẹ̀, kí ẹ má baa rẹ̀wẹ̀sì ni ọkàn yín, kí àárẹ̀ si mu yín.

4. Ẹ̀yin kò sáà tí ì kọ ojú ìjà si ẹ̀ṣẹ̀ títí dé títa ẹ̀jẹ̀ yin sílẹ̀ nínú ìjakadi yín.

5. Ẹ̀yin sì ti gbàgbé ọ̀rọ̀ ìyànjú tí ó n ba yin sọ̀rọ̀ bí ọmọ pé,“Ọmọ mi, ma ṣe aláìnánì ìbáwí Olúwa,kí o má sì ṣe rẹ̀wẹ̀sì nígbà tí a bá ń ti ọwọ́ rẹ̀ ba ọ wí:

6. Nítorí pé ẹni ti Olúwa fẹ́, òun ni i báwí,a sì máa na olukulùkù ọmọ tí òun tẹ́wọ́gba.”

7. Ẹ máa ní sùúrù lábẹ́ ìbáwí: Ọlọ́run bá wa lò bí ọmọ ni; nítorí pé ọmọ wo ni ń bẹ ti baba kì í báwí?

8. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin ba wà láìsí ìbáwí, nínú èyí tí gbogbo ènìyàn ti jẹ alábápín, njẹ́ ọmọ àlè ni yín, ẹ kì í sì ṣe ọmọ.

9. Pẹ̀lúpẹ̀lú àwa ni baba wa nípa ti ara tí o ń tọ́ wa, àwa sì ń bu ọlá fún wọn: kò ha yẹ kí a kúkú tẹríbà fún Baba àwọn ẹ̀mí, kí a sì yè?

10. Nítorí wọ́n tọ́ wa fún ọjọ́ díẹ̀ bí o ba ti dára lójú wọn; ṣùgbọ́n òun (tọ́ wa) fún èrè wa, kí àwa lè ṣe alábápín ìwà mímọ́ rẹ̀.

11. Gbogbo ìbáwí kò dábì ohun ayọ̀ nísinsìn yìí bí kò ṣe ìbànújẹ́; ṣùgbọ́n níkẹ́yìn yóò so èso àlàáfíà fún àwọn tí a tọ́ nípa rẹ̀, àní èso òdodo.

12. Nítorí náà ẹ na ọwọ́ tí o rọ, àti èékún àìlera;

13. “Kí ẹ sì ṣe ipa-ọ̀nà tí ó tọ́ fún ẹsẹ̀ yin,” kí èyí tí ó rọ má bá a kúrò lórí ike ṣùgbọ́n kí a kuku wò ó sàn.

14. Ẹ máa lépa àlàáfíà pẹ̀lú ènìyàn gbogbo, àti ìwà mímọ́, láìsí èyí yìí kò sí ẹni tí yóò rí Olúwa:

15. Ẹ máa kíyèsára kí ẹnikẹ́ni má ṣe kùnà oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run; kí “Gbòngbò ìkoro” kan máa ba hù sókè kí ó sì yọ yín lẹ́nu, ọ̀pọ̀lọpọ̀ a sì ti ipa rẹ̀ di àìmọ́.

16. Kí o má bá à si àgbérè kan tàbí aláìwà-bí-Ọlọ́run bi Èsau, ẹni tí o titorí òkèlè oúnjẹ kan ta ogún ìbí rẹ̀.

17. Nítorí ẹ̀yin mọ pé lẹ̀yìn náà, nígbà tí ó fẹ láti jogún ìbùkún náà, a kọ̀ ọ́, nítorí kò ri àyè ìronupìwàdà, bí o tilẹ̀ kẹ pé ó fi omijé wa a gidigidi.

18. Nítorí ẹ̀yin kò wá òkè tí a lè fi ọwọ́ kàn, àti ti iná ti ń jó, àti ti ìṣúdudu àti òkùnkùn, àti ìjì.

19. Àti ìró ìpè, àti ohùn ọ̀rọ̀, èyí tí àwọn tí o gbọ́ bẹ̀bẹ̀ pé, kí a má ṣe sọ ọ̀rọ̀ si i fún wọn mọ́:

20. Nítorí pé ara wọn kò lè gba ohun tí ó palaṣẹ, “Bí o tilẹ̀ jẹ ẹranko ni o farakan òkè náà, a o sọ ọ ni òkúta, tàbí a o gun un ní ọ̀kọ̀ pa.”

21. Ìran náà sì lẹ̀rù to bẹ́ẹ̀ tí Móṣè wí pé, “Ẹrù ba mi gidigidi mo sì wárìrì.”

Ka pipe ipin Àwọn Hébérù 12