Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Hébérù 12:19-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Àti ìró ìpè, àti ohùn ọ̀rọ̀, èyí tí àwọn tí o gbọ́ bẹ̀bẹ̀ pé, kí a má ṣe sọ ọ̀rọ̀ si i fún wọn mọ́:

20. Nítorí pé ara wọn kò lè gba ohun tí ó palaṣẹ, “Bí o tilẹ̀ jẹ ẹranko ni o farakan òkè náà, a o sọ ọ ni òkúta, tàbí a o gun un ní ọ̀kọ̀ pa.”

21. Ìran náà sì lẹ̀rù to bẹ́ẹ̀ tí Móṣè wí pé, “Ẹrù ba mi gidigidi mo sì wárìrì.”

22. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wá sí òkè Síónì, àti sí ìlú Ọlọ́run alààyè, ti Jerúsálémù ti ọ̀run, àti si ẹgbẹ́ àwọn áńgẹ́lì àìníye,

Ka pipe ipin Àwọn Hébérù 12