Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Hébérù 11:29-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

29. Nípa ìgbàgbọ́ ni wọn la òkun púpa kọjá bi ẹni pé ni ìyàngbẹ ilẹ̀: Ti àwọn ara Éjípítì dánwo, ti wọn sì ri.

30. Nípa ìgbàgbọ́ ni àwọn odi Jẹ́ríkò wo lulẹ̀, lẹ̀yìn ìgbà tí a yí wọn ká ni ijọ́ méje.

31. Nípa ìgbàgbọ́ ni Ráhábù panṣágà kò ṣègbé pẹ̀lú àwọn tí kò gbọ́ràn nígbà tí o tẹ́wọ́gba àwọn àmì ní àlàáfíà.

32. Èwo ni èmi o sì tún máa wí sí i? Nítorí pé ìgbà yóò kùnà fún mú láti sọ ti Gídíónì, àti Bárákì, àti Sámsónì, àti Jẹftà; àti Dáfídì, àti Sámúẹ́lì, àti ti àwọn wòlíì:

33. Àwọn ẹni nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ ti wọn sẹ́gun ilẹ̀ ọba, tí wọn ṣiṣẹ òdodo, ti wọn gba ìlérí, ti wọn dí àwọn kìnnìún lẹ̀nu,

34. Tí wọn pa agbára iná, ti wọn bọ́ lọ́wọ́ ojú idà, tí a sọ di alágbára nínú àìlera, ti wọn dí akọni ni ìjà, wọn lé ogun àwọn àjèjì sá.

35. Àwọn obìnrin ri òkú wọn gbà nípa àjíǹde: a sì da àwọn ẹlòmíràn lóró, wọ́n kọ̀ láti gba ìdásílẹ̀; kí wọn ba lè rí àjíǹde tí o dára jù gbà;

Ka pipe ipin Àwọn Hébérù 11