Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Hébérù 11:27-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

27. Nípa ìgbàgbọ́ ni o kọ Éjípítì sílẹ̀ láìbẹ̀rù ìbínú ọba: nítorí tí o dúró ṣinṣin bí ẹni tí ó n ri ẹni àìrí.

28. Nípa ìgbàgbọ́ ni ó da àsè ìrekọjá sílẹ̀, àti ìbùwọ́n ẹ̀jẹ̀, kí ẹni tí ń pa àwọn àkọ́bí ọmọ má báa fí ọwọ́ kan wọn.

29. Nípa ìgbàgbọ́ ni wọn la òkun púpa kọjá bi ẹni pé ni ìyàngbẹ ilẹ̀: Ti àwọn ara Éjípítì dánwo, ti wọn sì ri.

30. Nípa ìgbàgbọ́ ni àwọn odi Jẹ́ríkò wo lulẹ̀, lẹ̀yìn ìgbà tí a yí wọn ká ni ijọ́ méje.

Ka pipe ipin Àwọn Hébérù 11