Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Hébérù 11:20-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Nípa ìgbàgbọ́ ní Ísáákì súre fún Jákọ́bù àti Ísọ̀ níti ohun tí ń bọ̀.

21. Nípa ìgbàgbọ́ ni Jákọ́bù, nígbà ti o ń ku lọ, ó súrre fún àwọn ọmọ Jósẹ́fù ni ìkọ̀ọ̀kan; ó sì sìn ní ìtẹriba lé orí ọ̀pá rẹ̀.

22. Nípa ìgbàgbọ́ ni Jósẹ́fù, nígbà tí ó ń ku lọ, ó rántí ìjáde lọ àwọn ọmọ Ísraẹ́lì; ó sì pàṣẹ níti àwọn egungun rẹ̀.

23. Nípa ìgbàgbọ́ ní àwọn òbí Móṣè pa a mọ́ fún oṣù mẹ́ta nígbà tí a bí i, nítorí ti wọn rí i ní arẹwà ọmọ; wọn kò sì bẹ̀rù àṣẹ ọba.

Ka pipe ipin Àwọn Hébérù 11