Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Tímótíù 4:11-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Lúùkù nìkan ni ó wà pẹ̀lú mi, mú Máàkù wá pẹ̀lú rẹ: nítorí ó wúlò fún mi fún iṣẹ́-ìránṣẹ́.

12. Mo rán Tíkíkù ní iṣẹ lọ sí Éfésù.

13. Aṣọ òtútù tí mọ fi sílẹ̀ ní Tíróà lọ́dọ̀ Kárípù, nígbà tí ìwọ bá ń bọ̀ mu un wa, àti àwọn ìwé, pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ìwé-awọ.

14. Alekisáńdérù alágbẹ̀dẹ bàbà ṣe mi ni ibi púpọ̀: Olúwa yóò san án fún un gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀:

15. Lọ́dọ̀ ẹni tí kí ìwọ máa ṣọ́ra pẹ̀lú, nítorí tí ó kọ ojú ìjà sí ìwàásù wa púpọ̀.

16. Ní àkọ́kọ́ jẹ́ ẹjọ́ mi, kò sí ẹni tí ó ba mi gba ẹjọ́ rò ṣùgbọ́n gbogbo ènìyàn ni o kọ̀ mi sílẹ̀: Àdúrà mi ni kí a má ṣe ká à sí wọn lọ́rùn.

17. Ṣùgbọ́n Olúwa gba ẹjọ́ mi rò, ó sì fún mi lágbára; pé nipasẹ̀ mi kí a lè wàásù náà ní àwàjálẹ̀, àti pé kí gbogbo àwọn aláìkọlà lè gbọ́; a sì gbà mí kúrò lẹ́nu kìnìún náà.

18. Olúwa yóò yọ mí kúrò nínú iṣẹ́ bubúrú gbogbo, yóò sì gbà mí dé inú ìjọba rẹ̀; ẹni ti ògo wà fún láé àti láéláé. (Àmín).

19. Kí Parísíkà àti Àkúílà, àti ilé Onésífórù.

20. Érásítù wà ní Kọ́ríntí: ṣùgbọ́n mo fi Tírófímù sílẹ̀ ni Mílétù nínú àìsàn.

21. Sa ipá rẹ láti tètè wá ṣáájú ìgbà òtútù. Éúbúlù kí ọ, àti Páúdánì, àti Línù, Kíláúdíà, àti gbogbo àwọn ará-kùnrin.

22. Kí Olúwa wà pẹ̀lú ẹ̀mí rẹ kí oore-ọ̀fẹ́ wà pẹ̀lú yín. (Àmín).

Ka pipe ipin 2 Tímótíù 4